Awọn ẹlẹsin abalaye fẹhonu han nitori Eṣuleke tijọba fẹsun ipaniyan kan l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ẹlẹsin ibilẹ kaakiri ipinlẹ Ọṣun, Traditional Religion Worshippers Association State of Osun (TRWASO) lati ti parọwa sijọba lati ma ṣe gbe igbesẹ to le da omi alaafia ati ti iṣọkan to wa laarin awọn ẹlẹsinjẹsin ru.

Aarẹ ẹgbẹ naa, Dokita Oluṣeyi Atanda, lo sọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lasiko ipade alaafia ti awọn aṣoju ijọba ṣe pẹlu wọn ninu ile Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn to jẹ Araba Awo tilu Oṣogbo. O ṣalaye pe ọwọ tijọba fi n mu ọrọ wahala aarin awọn Eleegun atawọn ijọ Musulumi Kamọrudeen Society, le da wahala nla silẹ.

Atanda sọ pe ijọlọju lo jẹ pe lẹyin ti ile-ẹjọ fun awọn ti wọn wa lahaamọ ọlọpaa ni beeli ni ileeṣẹ to n ri si eto idajọ tun gbe atẹjade kan sita pe awọn yoo fi ẹsun ipaniyan kan Oloye Kayọde Eṣuleke.

O ni ko sẹni ti ko mọ pe nibikibi ti wahala ba ti bẹ silẹ, iru eyi to ṣẹlẹ ni Arayin Olude lọjọ naa, awọn ọmọ janduku maa n lo anfaani yẹn lati pitu ọwọ wọn, ko si sẹni to mọ ibi ti ibọn to pa Musulumi kan ti wa lọjọ naa.

O ni ko ṣee ṣe ki awọn maa woran gẹgẹ bii ẹlẹsin ibilẹ, ki alaiṣẹ ku sipo ẹlẹṣẹ, ẹnikẹni to ba si ni ẹri aridaju pe Baba Eṣuleke lo yinbọn lọjọ naa, ko mu un bọ sita, aijẹ bẹẹ, gbogbo awọn ẹlẹsin ibilẹ nijọba yoo ti mọle.

O sọ siwaju pe o ti di lemọlemọ Alhaji Qosim Yunus to jẹ oludasilẹ ijọ naa, ki i fẹ ki awọn ẹlẹsin miiran kọja nitosi ibi to ba wa lai ronu pe ofin ilẹ wa faaye gba ẹsin to ba wu onikaluku, bẹẹ ni ko sẹni to le di ẹnikan lọwọ lati kọja loju titi ijọba.

Atanda fi kun ọrọ rẹ pe “Yunus ṣekọlu si eegun Oriyọmi lọdun 2004, to si jẹ pe aafin ati ọdọ awọn ọlọpaa ni wọn ti yanju ẹ. Lọdun 2006, o da awọn babaalawo ti wọn n kọja duro, o ni wọn ko le kọja lẹgbẹẹ mọṣalaaṣi oun.

“O ba eegun Ogunleke ja lọdun 2008, o kan ẹni to gbe eegun naa lẹsẹ, ko si pẹ rara ti baba naa fi ku. Lọdun yii kan naa, o ba awọn onibẹmbẹ Ọṣun ja, bẹẹ lo leri pe oun yoo ba Arugba fa wahala. Oun yii kan naa lo ba awọn Oniṣango ja lọdun 2016, to si gbiyanju lati gba igba (calabash) ṣango lọwọ wọn. O ba eegun Ologbojo ja lọdun 2018, ko too waa ṣe eyi to ṣe fun eegun Eṣuleke lọdun yii”

Atanda waa rọ ijọba lati fi pẹlẹkutu mu ọrọ naa, ki wọn pepade lati fi ye gbogbo ẹlẹsin pe owo ki i fun owo lọrun. Ki ileeṣẹ eto idajọ si fi ọgbọn ati ododo ṣiṣẹ wọn.

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC l’Oṣun, Ọmọọba Gboyega Famọọdun, Kọmiṣanna fun ọrọ aṣa atibudo isẹmbaye (Dokita Simeon Ọbawale), Ọnarebu Sunday Akere, Ọnarebu Famurewa ati Oludamọran pataki fun gomina lori eto aabo, Abiọdun Ige, nijọba ran wa sibi ipade naa, gbogbo wọn ni wọn si fẹ ki awọn ẹlẹsin ibilẹ ṣe ṣuuru pẹlu ijọba lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply