Awọn eleyii dumbu iyawo ile n’Ijẹbu-Igbo, wọn tun ju oku ọmọ ẹ ti wọn pa si ṣalanga 

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Funra wọn ni wọn fẹnu ara wọn jẹwọ pe awọn lawọn ji iyawo ile kan torukọ ẹ n jẹ Modupẹọla Fọlọrunṣọ ati ọmọ ẹ, ọmọ ọdun mẹrin, to n jẹ Peter, gbe. Wọn lawọn dumbu wọn bii ẹran ni, awọn si dana sun ori iya, awọn gbe gbogbo ara ọmọ ẹ ju si ṣalanga!

Awọn ọkunrin meji yii, Ọlamide Odulaja (oun lo fẹẹ ṣoogun owo, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni) ati Baoku Gbuyi ti i ṣe babalawo to bẹ niṣẹ oogun owo ṣiṣe naa. Ẹni ọdun mọkandinlọgbọn loun ni tiẹ, ni wọn jẹwọ bẹẹ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣe ṣalaye ni pe ọkọ obinrin ti wọn ji gbe yii lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Ìjẹ̀bú-Igbo, iyẹn lọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun 2021 yii, pe iyawo atọmọ oun to ti kuro nile lọjọ kẹtala, oṣu naa, ko pada wale.

Eyi lawọn ọlọpaa ṣe kede pe awọn n wa Modupẹọla atọmọ ẹ, Peter, wọn si bẹrẹ si i ṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ wọn labẹnu.

Ninu iwadii naa ni wọn ti ri i pe afurasi ni Ọlamide Odulaja, kódà, Ibadan ni wọn ti pada ri i mu lori iku iya atọmọ naa.

O jẹwọ fawọn ọlọpaa pe oun ati babalawo oun to n gbe ni Japara, n’Ijẹbu-Igbo lawọn jọ ji Modupẹọla atọmọ ẹ gbe lọjọ kẹtala, oṣu keji, ọdun 2021.

Ọlamide sọ pe Baoku Gbuyi, babalawo oun, dana sun ori oloogbe ni, o si gun un mọ awọn nnkan mi-in to fẹẹ fi ṣoogun owo naa foun.

Wọn dele Baoku lati fọwọ ofin mu un, ṣugbọn o ti sa lọ nigba to ti gbọ pe wọn ti mu Ọlamide. Nigba naa lawọn ọlọpaa bẹrẹ si i wa a lati ẹkun kan sikeji, wọn si ri i mu labule Kajola, DPO Awa Ijẹbu pẹlu iranlọwọ awọn ọlọdẹ atawọn fijilante lo mu un.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ fawọn ọlọpaa, babalawo yii sọ pe Ọlamide lo waa ba oun pe oun fẹẹ ṣoogun owo, oun si ni ko lọọ mu ori eeyan wa gẹgẹ bii eelo toun yoo lo fun aajo ọla naa.

O lawọn jọ fẹnuko lati ji iya atọmọ yii gbe fun iṣẹ naa, awọn si dumbu wọn.

Baoku tẹsiwaju pe oun loun dana sun ori Modupẹọla, oun jo o pẹlu awọn eroja mi-in, oun si gbe e fun Ọlamide lati maa lo o.

Nipa bo ṣe ṣe oku Peter, ọmọ ọdun mẹrin. Babalawo yii sọ pe oun ju u si ṣalanga kan ni.

Pẹlu aṣiri nla tawọn ọlọpaa jẹ ko tu yii, CP Edward Ajogun gboriyin fun wọn fun iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ti wọn ṣe. O ni ki wọn ko awọn ọdaran mejeeji lọ sẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ fun iwadii si i, o si kilọ fawọn to n kanju owo pẹlu tulaasi pe ki wọn jawọ nibẹ.

Leave a Reply