Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Wọn ko parọ rara, iyẹn awọn gende mẹta tawọn ọlọpaa mu n’Ijẹbu-Ilese, nipinlẹ Ogun pe wọn fipa ba ọmọ ọdun mejidinlogun lo pọ. Wọn ni loootọ lawọn to tọnnu ibasun lori ọmọge naa lọjọ karun-un, oṣu kejila yii, awọn ro pe ko sọlọpaa niluu ti yoo mu awọn ni.
Awọn ọmọkunrin naa gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣe darukọ wọn ni: Tunde Sadiq Taiwo; ẹni ọdun mejilelogun, Damilọla Adeṣina, ẹni ogun ọdun ati Adegoke Amos; ẹni ọdun mọkanlelogun.
Yahoo lawọn ọmọkunrin yii gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe lawọn fura si wọn, nitori ọmọbinrin ti wọn fipa ṣe kinni fun naa ṣalaye pe bi ọjọ ori wọn ṣe kere to yii, mọto ayọkẹlẹ Lexus ES 350 ni wọn gbe wa, ti wọn fi dabuu ọna, ti wọn si fipa gbe oun wọnu ọkọ naa nigba toun n lọ si agbegbe Ita-Alẹ, n’Ijẹbu-ilese.
O ni ibi kan to wọn n pe ni Raṣanwa, n’Ijẹbu, kan naa ni wọn gbe oun lọ, ti wọn si ba oun lo pọ nikọọkan pẹlu ibọn ti wọn yọ soun.
Ọkan ninu awọn afipabanilopọ naa lawọn ọlọpaa kọkọ ri mu lẹyin ifisun ọmọbinrin yii, oun lo mu wọn lọ sibi ti wọn ti ri awọn meji yooku mu.
Nigba ti wọn n jẹwọ ẹṣẹ wọn f’ọlọpaa, awọn mẹtẹẹta sọ pe awọn fipa ba ọmọge yii lo pọ, nitori awọn ro pe awọn ọlọpaa ko si niluu lasiko yii, aṣegbe ni ibalopọ tulaasi naa yoo jẹ fawọn. Wọn lohun to jẹ kawọn ṣe e niyẹn.
Ṣa, CP Awolọwọ Ajogun ti jẹ ki wọn mọ pe ọlọpaa ko rebi kan, kọmiṣanna yii ti taari wọn sẹka itọpinpin, nibi ti wọn yoo ti mọ pe ọran gidi lawọn da.
Bẹẹ lo kilọ fawọn eeyan to n ro pe ko sọlọpaa niluu lati tun ero wọn pa, nitori wọn yoo bọ sọwọ ofin.