Awọn eleyii fipa ba obinrin sun l’Ogijo, wọn tun fidio rẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ṣọla Ọlaoluwa, Ibrahim Kẹhinde ati Lukman Banjoko lẹ n wo yii, awọn pẹlu awọn meji mi-in tọwọ ko ti i ba ni wọn fi ẹtan mu ọmọbinrin kan mọlẹ l’Ogijo, nipinlẹ Ogun, wọn ba a lo pọ nikọọkan ejeeji, wọn si tun fidio ere egele ọhun lọjọ kẹtalelogun, oṣu keje yii.

Ọmọbinrin ti wọn ba lo pọ naa lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Ogijo, o ni ọkan ninu wọn ti wọn n pe ni Enny Money loun kọkọ mọ, oun lo juwe ibi kan toun yoo ti pade alaaanu lori ayelujara foun, oun si lọ si ẹka to ni oun yoo ti ba alaaanu ọhun pade.

Ọmọge naa ṣalaye pe aṣe Enny Money naa lo ni oju opo ọhun, boun ati ẹ ṣe n sọrọ nibẹ lo ni koun wa si agbegbe Idimogun, l’Ogijo, afi boun ṣe debẹ to mu oun wọ inu ile kan ti gende marun-un wa, bi gbogbo wọn ṣe to tọọnu ibasun lori oun niyẹn pẹlu ipa.

Ibọn kan ni wọn fa yọ ti wọn fi dẹru ba a gẹge bo ṣe wi, ohun to si waa buru nibẹ ni pe bi wọn ṣe n ba oun sun nikọọkan ni wọn n kamẹra rẹ silẹ lori foonu wọn.

Ọjọ keji ti wọn fipa ṣe kinni naa lọwọ ba awọn mẹta tẹ ẹ n wo yii, ibọn onike ti wọn n lo ati foonu lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn.

Ọga ọlọpaa tuntun nipinlẹ Ogun, CP Awolọwọ Ajogun, ti ni ki wọn wa awọn meji to ku ri, kawọn tọwọ ba yii si maa lọ sẹka ọtẹlẹmuyẹ (SCID) to n tọpinpin iwa ọdaran.

Leave a Reply