Awọn eleyii lọ jiiyan gbe l’Ekiti, ile-ẹjọ ti ran wọn lẹwọn gbere 

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ki awọn mẹrin kan, Adeoye Sunday, Adewusi Dare, Bamigboye Damilọla ati Ogunlayi Ṣeun, maa lọ si ẹwọn gbere pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun igbimọ-pọ lati jale ati ijinigbe.

Iwaju Onidaajọ Lekan Ogunmoye, ni wọn ko wọn lọ. Ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹsan, ọdun 2017, ni wọn ṣẹ ẹṣẹ ti wọn n gba ifajọ le lori yii niluu Ikẹrẹ-Ekiti, pẹlu bi wọn ṣe ji Arabinrin Florence Popoọla, to jẹ ẹni ọdun marunlelọgọrin (75) gbe ninu ile rẹ, ti wọn si gbee pamọ sinu igbo kan to wa laarin Eyio-Ekiti ati Awọ-Ekiti, fun odidi ọjọ mẹrin, ti wọn si gba miliọnu kan aabọ Naira lọwọ rẹ.

Ọwọ ọlọpaa tẹ awọn ọdaran ọhun lasiko ti wọn wọ wọn lọ ile-ẹjọ lori ẹsun miiran to jọ mọ igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi ati idigunjale. Ẹsun wọnyi nile-ẹjọ juwe pe o lodi sofin ipinlẹ Ekiti, ti wọn kọ lọdun 2004, ati ofin ijinigbe ti wọn kọ nipinlẹ naa lọdun 2015.

Agbefọba, Ọgbẹni Julius Ajibola, pe ẹlẹrii mẹrin, bakan naa lo tun ko awọn ohun ti wọn fi gba ohun awọn ọdaran naa silẹ gẹgẹ bii ẹsibiiti lati fi idi ẹjọ rẹ mulẹ ṣinṣin.

Nigba ti awọn afurasi ọdaran yii n sọrọ lati ẹnu awọn agbẹjọro wọn, Ọgbẹni Chris Ọmọkare ati Sunday Ochai, wọn ko pe ẹlẹrii Kankan, ṣugbọn wọn bẹ ile-ẹjọ lati ṣiju aanu wo wọn.

Ninu idajọ rẹ, o sọ pe agbefọba naa ti ṣe ohun gbogbo lati fidi ẹjọ rẹ mulẹ ṣinṣin. Bakan naa lo tun fidi ẹsun ijinigbe ti wọn fi kan awọn ọdaran naa mulẹ pẹlu.

Lẹyin gbogbo atotonu, adajọ naa paṣẹ pe ki ọdaran yii lọọ lo iyooku aye wọn lọgba ẹwọn.

Leave a Reply