Awọn eleyii lọọ jale laarin awọn ti wọn n ṣewọde, ni wọn ba pokọ iya fun wọn

Faith Adebọla, Eko

Ojo iya buruku lo rọ sori awọn janduku mẹta yii, Sulaimọn Ayinde, Damilola Balogun ati Niyi, ti wọn yọ kẹlẹ wọ aarin awọn ọdọ to n ṣe iwọde tako awọn ọlọpaa SARS lọsan-an Ọjọbọ, Wẹsidee yii.

Ọkan lara awọn to n ṣe iwọde naa, Ṣẹgun, to ba akọroyin ALAROYE sọrọ nibi iṣẹlẹ ọhun sọ pe oun loun kọkọ pade awọn mẹtẹẹta nigba ti wọn fẹẹ dara pọ mọ awọn to n ṣe iwọde naa, oun fura si wọn tori irisi wọn ko jọ ti ọmọluabi, o ni wọn tọrọ owo lọwọ oun, oun si fun wọn ni ẹẹdẹgbẹta naira, oun ni ki wọn pada sibi ti wọn ti n bọ.

Ṣẹgun ni ko pẹ lẹyin toun ti kuro lọdọ wọn lẹnikan figbe ta laarin ero rẹpẹtẹ naa pe wọn ti yọ foonu lapo oun o, bawọn si ṣe wo raa-raa-ra yika bayii loun ti ri ọkan ninu wọn to n sa lọ, lawọn ọdọ naa ba gba ya a, titi ti wọn fi le e mu.

Wọn tun mu awọn meji mi-in pẹlu rẹ, wọn ni wọn ba aake pompo kan ti ọkan lara wọn yọ lati fi gba ara ẹ silẹ nigba ti wọn fẹẹ mu un, ṣugbọn awọn ọdọ naa bori ẹ, bẹẹ ni wọn tun ba ọbẹ ati ada lara ẹni kẹta wọn.

Ibinu iwa ole ti wọn hu yii lo mu ki wọn ṣina iya fun wọn, lẹyin eyi ni wọn wọ wọn wa sẹnu geeti ileegbimọ aṣofin.

Awọn ọlọpaa to wa nibẹ ko kọkọ fẹẹ ṣi geeti fun wọn, ṣugbọn nigba ti wọn ri i pe awọn ọdọ naa le fibinu lu wọn pa sẹnu geeti ọhun ni wọn ba jẹ ki wọn wọ awọn ọdaran naa wọle, ti wọn si pe awọn ọlọpaa teṣan Alausa lati waa ko wọn.

Ọkan ninu awọn ọdọ to n ṣe iwọde naa sọ pe ifẹhonu han wọọrọwọ lawọn n ṣe, o ni oun fẹ kawọn ọlọpaa wadii awọn ọdaran yii daadaa, tori o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn kan lo ran wọn lati waa huwa janduku ati ole jija, kijọba le ri nnkan kẹwọ lati tako iwọde ti wọn gun le naa.

Leave a Reply