Awọn eleyii n gbowo ipa lọwọ awọn onimọto, wọn loṣiṣẹ ijọba Eko lawọn

Faith Adebọla, Eko

Ọrẹ timọtimọ ni awọn ọkunrin mẹrin yii, Taiwo Falọdun, ẹni ọdun mejidinlaaadọta, Adedire Ọlaniyi, ẹni ọdun mejilelogoji, Fẹmi Ọṣunkọya, ẹni ọdun mẹtalelaaadọta ati Ọlawale Edu, ẹni ọdun mọkanlelaaadọta, ṣugbọn rikiṣi lo pa wọn pọ ti wọn fi dọrẹ, iṣẹẹbi ti wọn fẹsun ẹ kan wọn ni pe wọn n gbowo ipa lọwọ awọn onimọto l’Ekoo, wọn ni oṣiṣẹ ijọba lawọn, awọn lawọn n ri si ọkọ to dẹnu kọlẹ nibi ti ko yẹ.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Ẹti, Furaidee yii, SP Benjamin Hundeyin sọ pe niṣe lawọn oṣiṣẹ yii mu mọto kan mọlẹ nibi ti onimọto naa gbe e si niwaju ile Elephant Cement, to wa n’Ikẹja, wọn ni ọkọ naa ti di alopati, ijọba o si nifẹẹ siru awọn alopati ọkọ bẹẹ lati wa loju popo, tori naa, awọn maa wọ ọkọ naa lọ.
Wọn sọ fonimọto naa pe ti ko ba fẹ kawọn wọ ọkọ rẹ lọ, ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (N50,000) lawọn maa gba lọwọ ẹ, wọn ni owo tijọba ni kawọn gba niyẹn, wọn si mu risiiti ayederu kan ti wọn tẹ ontẹ ijọba si dani.
Nibi ti ibẹru ti mu obinrin onimọto yii de lo fi ke sawọn ọrẹ rẹ lori aago, o fi iṣẹlẹ naa to wọn leti, lawọn yẹn ba ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo, kia lawọn agbofinro ikọ ayara-bii-aṣa RRS, (Rapid Response Squard) ti lọọ ka wọn mọbẹ.
Wọn kọkọ mu olori awọn afurasi ọdaran naa, Taiwo Falọdun, bi wọn ṣe n wọ ọ ju si mọto ọlọpaa ni Ọlalekan Ẹdu yọju lati bẹbẹ fun un, ni wọn ba mu oun naa, titi ti wọn fi mu awọn mẹrẹẹrin.
Nigba ti wọn bẹrẹ iwadii, ayẹwo ati akọsilẹ RRS fihan pe awọn araabi yii o ṣẹṣẹ bẹrẹ iwa jibiti ti wọn n hu yii, wọn ti wa lẹnu ẹ tipẹ, wọn si ti figba kan wa ni akolo ọlọpaa ri lọdun 2020 ti wọn mu wọn fun ẹsun lilu ọjọgbọn fasiti kan ni jibiti owo gọbọi kan, ti wọn purọ pe oṣiṣẹ kansu lawọn.
Wọn tun fẹsun kan Adedire ati Oṣunkọya pe wọn n gbowo lọwọ awọn onimọto loju popo, wọn n mu awọn ọlọkọ to ba paarọ ọna lọna marosẹ LASU si Igando.
Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, CP Abiọdun Alabi, ti paṣẹ pe ki ọga agba ikọ RSS, Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi, taari awọn afurasi naa sile-ẹjọ, ki wọn lọọ ṣalaye ara wọn niwaju adajọ.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: