Lẹyin tawọn eleyii pa ọga olotẹẹli n’Ijẹbu, wọn tun fẹẹ jiyawo atọmọ ẹ gbe

Gbenga Amos, Abẹokuta

 Bi wọn ba leeyan ya ika, afibi-ṣoloore ati ọdaju, gbogbo ẹ lo pe sara tọkọ-taya afurasi ọdaran tọwọ awọn agbofinro ipinlẹ Ogun ṣẹṣẹ tẹ yii, Larry Adebayọ Adewunmi, iyawo ẹ, Okereke Oluwafunmilayọ Adewunmi, ati ọrẹ imulẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ ibi, Sanni Adebọwale. Iṣẹ ijinigbe gbowo ni wọn sọ diṣẹ aṣela, wọn o tun fi mọ lori ijinigbe nikan o, niṣe lawọn n pa ẹnikẹni ti wọn ba ji gbe lẹyin ti wọn ba ti gbowo lọwọ awọn mọlẹbi ẹ, wọn ni kaṣiiri awọn maa baa tete tu lawọn ṣe n ṣe bẹẹ, ṣugbọn ọtafa-soke-yi’do-bori, b’ọba aye o ri ọ, t’ọrun n wo wọn.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi ṣọwọ s’Alaroye l’Ọjọbọ, Tọsidee ọsẹ yii, o ni latigba tawọn amookun-ṣika ẹda kan ti ji oludasilẹ ati alakooso otẹẹli Rolak, to wa n’Ijẹbu-Ode, Ọtunba Smith Ajayi, gbe lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2020, ti wọn si yinbọn pa a lẹyin ti wọn gba miliọnu mẹẹẹdogun Naira tan lọwọ awọn eeyan ẹ, lawọn agbofinro ti n dọdẹ awọn olubi ẹda to ṣika ọhun.

O ni nnkan bii aago meje aabọ aṣaalẹ ọjọ naa ni wọn ji Ajayi gbe nile rẹ to wa l’Ẹsiteeti Anifowoṣe, ni Igbẹba, Ijẹbu-Ode, ti wọn si kan sawọn mọlẹbi pe ki wọn lọọ wa owo itusilẹ wa. O lawọn ọlọpaa ṣapa gidigidi lati yọ oloogbe naa lakata awọn to ji i gbe, ṣugbọn bi wọn ṣe n ṣe eyi lọwọ lawọn ajinigbe naa gbẹmi lẹnu ọkunrin ọhun, lẹyin ti wọn ti gba miliọnu mẹẹẹdogun owo itusilẹ tan.

Amọ, awọn ọlọpaa yii o jawọ o, SP Taiwo Ọpadiran to lewaju ikọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ẹka ti wọn ti n gbogun ti iwa ijinigbe nileeṣẹ ọlọpaa naa n ba iwadii ijinlẹ ati ifimufinlẹ wọn lọ. Ọdun meji ti gori iṣẹlẹ naa k’Ọlọrun too deṣẹ wọn lade. Olobo ta wọn pe awọn olubi ẹda kan yii ti tun n dọdẹ ẹmi iyawo oloogbe naa, Yeye Oluṣọla Roseline Ajayi, wọn fẹẹ ji oun atọmọ rẹ gbe.

Iwadii ijinlẹ ti wọn ṣe fihan pe ọkan lara awọn arufin naa ko si nipinlẹ Ogun, wọn ni ilu Ikeji Arakeji, nipinlẹ Ọṣun, lo n gbe, o maa n wọ ipinlẹ Ogun ti wọn ba ti ni ọpureṣọn buruku ti wọn fẹẹ ṣe ni, ti yoo si tun pada ti wọn ba ti ṣe e tan. Awọn ọtẹlẹmuyẹ tẹkọ leti lọ sibẹ, wọn si fọwọ ṣikun ofin mu agbalagba ẹni ọdun marundinlaaadọta ọhun, Ọgbeni Adebọwale Sanni.

Sanni yii lo jẹwọ fawọn ọlọpaa pe loootọ loun n dọdẹ aya oloogbe ti wọn sọ naa, o lawọn fẹẹ ji i gbe, kawọn si gbowo nla lọwọ ẹ ni, amọ oun kọ loun pilẹṣẹ iṣẹ ero buruku naa, o lọmọọṣẹ lasan loun, lo ba darukọ Larry Adebayọ Adewunmi atiyawo ẹ. O ni Larry lolori ikọ ajinigbe awọn, o ni otẹẹli Ọgbẹni Ajayi si niyawo rẹ ti n ṣiṣẹ, obinrin naa lo si juwe bawọn ṣe rin in tọwọ wọn fi tẹ ọga rẹ lọjọsi.

O tun jẹwọ pe Larry lo paṣẹ kawọn pa olotẹẹli naa lẹyin tawọn gbowo tan, tori ageku ejo ti i ṣoro bii agbọn lọkunrin naa yoo jẹ fawọn tawọn bi tu u silẹ, o lo le jẹ kọwọ awọn agbofinro tete tẹ awọn, lawọn fi yan-n-ke ẹ danu.

O ni iyawo Larry yii tun mọ ọpọ awọn ileeṣẹ okoowo oloogbe naa ati tiyawo ẹ, tori o ṣi n ba wọn ṣiṣẹ nileetaja ti wọn ti n ta ohun eelo ikọle, tawọn yẹn o si mọ pe awọn ti kẹran-mero, pe ọdalẹ paraku ti wa laarin awọn oṣiṣẹ ti wọn fọkan tan. O loun lo si n sọ bawọn ṣe maa rin in lati ri iyawo rẹ gbe, ṣugbọn ko ti i ṣe e ṣe ti wọn fi waa mu oun yii.

Bi iwadii ṣe n tẹsiwaju, Sanni ran awọn ọtẹlẹmuyẹ lọwọ lati mu Larry, ṣugbọn ọdaran naa kọkọ yari mọ wọn lọwọ pe oun mọ ẹnikẹni to n jẹ Sanni tabi Ajayi ati idile rẹ ri, o loun o tiẹ le pa eṣinṣin debi toun maa paayan, ọmọ ilu Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun, loun, oun si niṣẹ gidi lọwọ ni toun.

N ni wọn ba foju ẹ rinju pẹlu Sanni, wọn ni bo ṣe ri Sanni lakolo awọn ọlọpaa ni kẹkẹ pa mọ atioro ẹ lẹnu, lo ba bẹrẹ si i jẹwọ iwa laabi to ti hu, o si sọ pe ootọ ni gbogbo ọrọ ti Sanni ti sọ fun wọn ṣaaju.

Iwadii tun taṣiiri Larry pe ogbologboo onijibiti ẹda ni tẹlẹ, ko too ya sidii okoowo ijinigbe, o si jọ pe o riṣe nidii ẹ daadaa, lo ba tẹra mọ ọn. Wọn ni iṣẹ tiẹ ni lati wadii awọn eeyan to ri jajẹ lawujọ, yoo wadii irinsi ati igbokegbodo wọn, lẹyin eyi ni yoo fun Sanni lọwọ, lati ji wọn gbe, oun naa lo maa n gbowo itusilẹ, ti wọn yoo si pin in lẹyin-ọ-rẹyin, amọ o ti sọ pe gbogbo awọn toun ba ji gbe, afi koun pa wọn, kawọn ọlọpaa ma baa le tọpasẹ awọn, tori ko fẹ kaṣiiri awọn tete tu.

Iwadii tun fihan pe akaunti banki meji ni Larry n lo ni banki, ibẹ ni wọn lo maa n tọju owo to ba pa nidii jiji-i-yan gbe si. Wọn loun lo ni akaunti kan ni banki JAIZ, ti nọmba rẹ jẹ 0010913206, owo to din diẹ ni miliọnu marundinlogoji Naira (N34,953,455) ni wọn ba ninu asunwọn rẹ ni banki naa, o si tun ṣi akaunti mi-in si Access Bank, miliọnu mẹrin, ẹgbẹrun lọna ọrinlelẹẹẹdẹgbẹta din mẹrin, ojilelẹgbẹrin ati mẹfa Naira (N4,576,846) lo na ku ninu eyi. Wọn si tun ba mọto bọginni Toyota Highlander kan to fi n jaye kiri.

Bakan naa lọwọ ti ba iyawo rẹ, ibiiṣẹ to ti ṣe bii oṣiṣẹ gidi, ṣugbọn to n ṣe wọn ni ṣuta labẹnu naa ni wọn ti lọọ mu un, ẹsẹ awọn mẹtẹẹta si ti pe sakata awọn ọtẹlẹmuyẹ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle ti kan saara gidi si iwadii ijinlẹ tawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ yii ṣe, bi wọn ṣe fẹsọ tuṣu desalẹ ikoko ti wọn fi ri awọn afurasi ọdaran naa mu. O ni iwadii yoo tubọ tẹsiwaju ki wọn le ṣawari awọn yooku ti wọn jọ n gbimọ-pọ lati huwa ọdaran. Bakan naa lo lawọn maa juwe ọna ile-ẹjọ fawọn tọwọ ba yii tiwadii ba ti pari, ki wọn le fimu kata ofin ni kootu.

Leave a Reply