Ọrẹoluwa Adedeji
Ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan bayii ni tolohun, bẹẹ lọrọ ri fun ọkunrin kan ati obinrin kan, Steve Green, ẹni ọdun mejidinlogoji, ati Aduago Darlington, nipinlẹ Rivers ti ọwọ tẹ laipẹ yii.
Niṣe lawọn mejeeji yoo dọgbọn bii pe ero to fẹẹ wọ kẹkẹ NAPEP ni wọn, ni wọn yoo ba wọnu ẹ. Bi wọn ba ti wọnu rẹ ti wọn rin diẹ ni wọn yoo ba yọ ada, ọbẹ atawọn ohun ija oloro mi-in si awọn ero to wa nibẹ pe ki wọn ko gbogbo ohun to wa lọwọ wọn wa. Lẹyin naa ni wọn yoo ṣẹṣẹ waa gba kẹkẹ NAPEP yii lọwọ ẹni to n wa a, ti wọn yoo si gbe e sa lọ.
O ti pẹ ti awọn mejeeji yii ti maa n ṣe bẹẹ gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Rivers, Grace Iringe-Koko, ṣe sọ. Wọn ni niṣe leyi to jẹ obinrin yii yoo ṣe bii alaboyun ti ara ni. Ipo to wa yii lọpọ onikẹkẹ NAPEP fi maa n tete duro fun un, nigba to ba si wọle tan ni wọn maa too mọ pe adigunjale ni.
Grace ni ori ere ni wọn ti maa n ja awọn ero to ba wa ninu kẹkẹ naa pẹlu dẹrẹba silẹ, ti wọn yoo si sa lọ pẹlu kẹkẹ ọhun.
Ṣugbọn kẹkẹ ọkunrin kan ti wọn n pe ni Lasisi Akeem ti wọn ji lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta to ṣẹṣẹ pari yii, laduugbo kan ti wọn n pe ni Rumunduru Eneka, to wa nijọba ibilẹ Obi/Akpor, nipinlẹ naa lọwọ fi tẹ wọn.
Awọn ọlọpaa ti wọn n ṣe patiroolu kaakiri adugbo naa ni wọn ri ọkunrin yii pẹlu ọju ọgbẹ yannayanna lara rẹ, ni wọn ba duro beere ohun to ṣẹlẹ. Akeem lo ṣalaye iṣẹlẹ naa fawọn ọlọpaa, to si juwe awọn ti wọn ṣa a ladaa ọhun.
Oju-ẹsẹ ni awọn agbofinro gbe ọkunrin ti wọn ṣa niṣakuṣaa yii lọ sileewosan, ti wọn si lepa awọn to ṣiṣẹ ibi naa lọ.
Ko pẹ rara tọwọ fi te meji ninu wọn, ti wọn si ri kẹkẹ onikẹkẹ ti wọn ji gba pada. Bẹẹ ni wọn si ti bẹrẹ si i wa awọn meji to ku ti wọn jọ n ṣiṣẹ naa gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa naa ṣe sọ.