Awọn ẹsọ amọtẹkun gbẹsẹ le maaluu igba (200) to ba oko oloko jẹ n’Irẹsẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Awọn maaluu to to bii igba (200) lawọn ẹsọ amọtẹkun ẹka tipinlẹ Ondo gbẹsẹ le lẹyin ti wọn ba nnkan ọgbin agbẹ kan ta a forukọ bo laṢiiri jẹ niluu Irẹsẹ, nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ.

Alakooso ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ṣalaye fun akọroyin ALAROYE pe ori lo ko ọkunrin agbẹ naa yọ lọwọ awọn Fulani ọhun lasiko to ba wọn nibi ti wọn ti n fi ẹran ọṣin wọn ba nnkan oko rẹ jẹ.

Dipo tawọn darandaran naa iba si fi tọrọ aforiji nigba to n fi aidunnu rẹ han lori oko rẹ ti wọn bajẹ, ibọn ni wọn fa yọ, ti wọn si fẹẹ yin in mọ ọn ko too raaye sa mọ wọn lọwọ.

Lẹyin eyi lọkunrin agbẹ ọhun mori le ọfiisi ẹsọ Amọtẹkun to wa nijọba Ifẹdọrẹ lati lọọ fẹjọ awọn janduku naa sun.

Bi wọn ṣe ri awọn ẹṣọ Amọtẹkun ni wọn sa lọ, leyii to mu ki wọn fi pampẹ ofin gbe gbogbo maaluu ti wọn ba ninu oko oloko yii.

Oloye Adelẹyẹ ni awọn ti kan sì olori awọn Fulani to wa lagbegbe naa, to si ti jẹ ki awọn mọ pe awọn darandaran meji, Muhammed Abu ati Musa Saliu, ni wọn wa nidii iṣẹlẹ ọhun.

O ni darandaran tọwọ ba tẹ pe o ko ẹran jẹ nita gbangba lodi sofin tijọba ipinlẹ Ondo fi lelẹ ko ni i lọ lai jiya to tọ labẹ ofin.

 

 

Leave a Reply