Awọn FRSC  naa ti fẹẹ maa lo ibọn o

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Federal Road Safety Corps(FRSC), iyẹn ajọ ijọba apapọ to n ri si aabo loju popo naa ti n pete ati maa lo ibọn lẹnu iṣẹ wọn bayii, nitori wọn ni awọn ọlọkọ maa n dunkooko  mọ awọn nigba mi-in.

Awọn ọmọ ile-igbimọ aṣoju to n ri si ọrọ to ba kan FRSC l’Abuja ni wọn gbe aba yii kalẹ l’Ọjọbọ, ọjọ karun-un, oṣu kọkanla yii, lasiko ti wọn n ṣagbeyẹwo eto iṣuna ajọ naa fun ọdun 2020 ati 2021.

Alaga igbimọ naa, Akinfọlarin Mayọwa, sọ pe ofin ajọ FRSC ti ọdun 1992, faaye gba awọn oṣiṣẹ yii lati lo ibọn lẹnu iṣẹ wọn.  O lo yẹ ki wọn tiẹ maa lo o nisinyii kawọn eeyan le maa tẹle ofin.

Akinfọlarin sọ pe igbimọ yii yoo ṣepade pẹlu akọwe ijọba apapọ, Boss Mustapha, awọn yoo si kọwe si Aarẹ Muhammadu Buhari lati sọ aba naa di ofin.

Bakan naa ni ọkan ninu awọn igbimọ naa, Solomon Maren, sọ pe ewu pọ loju ọna Naijiria ju ki awọn FRSC ma lo ibọn lọ. O lawọn yoo ba ọga ọlọpaa, IGP Muhammed Adamu, sọrọ lori ọrọ onibọn yii.

Ọga agba pata fawọn FRSC, Bọboye Oyeyẹmi, naa sọ pe lilo ibọn yoo din jagidijagan tawọn oṣiṣẹ oun n koju ku, yoo si da aabo bo wọn.

One thought on “Awọn FRSC  naa ti fẹẹ maa lo ibọn o

Leave a Reply