Awọn Fulani agbebọn tun ṣigun wọ’lu Igangan, wọn pa olori ẹṣọ Amọtẹkun kan atawọn meji mi-in

Faith Adebọla

Jinnijinni ati ibẹru-boju tun gbode lawọn niluu Igangan, Tapa, Ayetẹ ati Igbo-Ọra, lagbegbe Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, pẹlu bawọn Fulani agbebọn ṣe tun ya bo awọn ilu naa lọjọ Ẹti, Furaidee yii, ti wọn si pa olori ẹṣọ Amọtẹkun nijọba ibilẹ Ibarapa Kọmureedi Muritala Adenrele, ateeyan meji mi-in, ki wọn too sa lọ.

Ba a ṣe gbọ, ni nnkan bii aago mẹfa si meje irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, lawọn Fulani apanijaye ẹda naa ya wọ ilu Igangan, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, wọn ni ọna marosẹ Abẹokuta si Igbo-Ọra ni gba wa, wọn dihamọra ogun gidi ni, aṣọ awọn ṣọja ati kọsitọọmu ni gbogbo wọn wọ, ọkọ akẹru Toyota Hilux meji, bọọsi Họnda elero mejidinlogun kan, ati ọkọ Toyota Sienna kan ni wọn kun inu rẹ bamu.
Olori ẹṣọ Amọtẹkun nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa (ti ko fẹ ka darukọ oun) to ba ALAROYE sọrọ lori iṣẹlẹ yii sọ pe nigba tawọn agbebọn naa n bọ, awọn ẹṣọ imigireṣọn to wa loju ọna, nikọja ilu Tapa da wọn duro, wọn bi wọn leere ẹni ti wọn jẹ, ṣugbọn bi wọn ṣe mura bii ṣọja ati kọsitọọmu ko jẹ ki wọn ṣayẹwo wọn daadaa ti wọn fi fi wọn silẹ.

Ohun kan naa lo ṣẹlẹ nigba ti wọn de ọdọ awọn ọlọpaa ikọ ‘Ọpureṣọn Burst’ to wa nitosi odo Ofiki ni ati wọ Igangan, awọn naa da wọn duro, ṣugbọn wọn ko fura pe wọn ki i ṣe ojulowo ṣọja ati kọsitọọmu, pe wọn fẹẹ lọọ ṣiṣẹẹbi kan ni.

Gẹrẹ ti wọn de ilu Igangan ni aṣaalẹ naa, wọn kọkọ duro ni adugbo AUD Quarters, ni abawọle siluu naa, wọn lawọn agbesunmọmi yii to ọgọrun-un kan aabọ.

Ọkunrin ọlọdẹ kan to n ṣiṣẹ sikiọriti adugbo ọhun lọọ ba wọn lati beere iru ẹni ti wọn jẹ, ati idi ti wọn fi duro sibẹ, ṣugbọn iro ibọn lau lawọn eeyan gbọ, ki wọn to mọ ohun to n ṣẹlẹ, wọn ti pa sikiọriti naa danu, ni wọn ba bẹrẹ si i yinbọn ni koṣẹkoṣẹ.

Iro ibọn yii lo mu kawọn eeyan bẹrẹ si i kan siraawọn lori ẹrọ alagbeeka pe ogun ti wọlu o, ṣugbọn wọn ni ojo arọọda to waye lọjọ naa ko jẹ ki ipe ja geere, ọpọ awọn eeyan si ni nọmba ipe wọn ko wọle.

Sibẹ, awọn fijilante, awọn ọlọdẹ ilu, awọn ọmọ OPC ati ẹṣọ Amọtẹkun sare ṣa ara wọn jọ, wọn si bẹrẹ si i gbegi dina lati mura ija de awọn afẹmiṣofo yii. Bakan naa ni wọn bẹrẹ si i pe awọn ẹṣọ alaabo yooku lawọn ilu tawọn Fulani agbebọn naa ti gba kọja lori aago, pe ki wọn gbaradi.

Boya wọn fura ni o, a gbọ pe lẹyin iṣẹju diẹ ti wọn ti n yinbọn, awọn janduku naa ko si mọto wọn, wọn si ṣẹri pada.

Bi wọn ti n lọ, nigba ti wọn de ọdọ awọn kọsitọọmu ti wọn ti kọja tẹlẹ, wọn da ibọn bolẹ, wọn si fibọn ṣe meji lara wọn leṣe yannayanna. Wọn lawọn mejeeji ọhun ṣi wa lọsibitu bayii nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.
Nigba ti wọn yoo fi kọja ni ilu Tapa si Ayetẹ, awọn eeyan ti lọọ gbe igi dina fun wọn. Wọn lawọn Fulani naa tun bẹrẹ si i yinbọn bi wọn ṣe bọ silẹ lati ko igi ati okuta to wa lọna kuro. A gbọ pe mẹta ninu awọn ọkọ naa ti kọja tan, ẹkẹrin to jẹ bọọsi akero lo fẹẹ kọja, lawọn ẹṣọ alaabo ilu naa ti fibọn pade wọn bo tilẹ jẹ pe wọn ko yọju si wọn, wọn yinbọn fun taya ọkọ naa, lawọn janduku ẹda yii ba rọ da silẹ, awọn naa yinbọn, wọn si fọn ka sigbo, wọn fi ọkọ wọn silẹ, wọn sa lọ.

A gbọ pe lasiko ti wọn n yinbọn ọhun ni ibọn awọn Fulani ba ọkunrin ọlọdẹ kan ti wọn porukọ ẹ ni Sulaimọn, wọn labẹ ni ibọn naa ti ba a, ẹsẹkẹsẹ lo si dagbere faye.

Wọn ni bọọsi Họnda ọhun wa lọdọ awọn Ọpureṣọn Burst niluu Ayetẹ, ṣugbọn wọn o ti i ri eyikeyii mu ninu awọn to sa wọgbo.

Kawọn eeyan naa to de ilu Idere, awọn araalu ti gbegi dina fun wọn bakan naa, ṣugbọn wọn bọ silẹ, wọn ko awọn igi naa kuro, wọn sa lọ.

Bi wọn ti tẹsiwaju de ilu Igbo-Ọra, wọn tun ba idena pade, mọto Amọtẹkun, igi ati okuta ni wọn gbe dina fun wọn, ṣugbọn awọn Fulani agbebọn naa tun ṣe bakan naa, wọn bọ silẹ, wọn ṣina ibọn bolẹ lati le gbogbo awọn eeyan sa, wọn si bẹrẹ si i ko awọn nnkan idena naa kuro.

Olori ẹgbẹ OPC n’Ibarapa, Kọmureedi Adedeji Oluwọle sọ f’ALAROYE pe wọn fibinu yinbọn fun mọto Amọtẹkun ọhun, wọn ba a jẹ gidi, wọn tun ṣi bọnẹẹti ọkọ, wọn da ibọn bo ẹnjinni ọkọ naa, wọn si fọ ẹnjinni ati agbari ọkọ naa, ki wọn too ti i sẹgbẹẹ kan, ti wọn si sa lọ.

Olori ẹṣọ Amọtẹkun nijọba ibilẹ Aarin-Gbungbun Ibarapa, Ọgbẹni Muritala Ajasa to n gbe ọkada bọ lati wo ohun to n ṣẹlẹ, niṣe ni wọn fibọn pade ẹ, ti wọn si pa a lẹyẹ-o-sọka.
Lẹyin ti wọn kọja tan, wọn ni ọna Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, ni wọn kọri si, bẹẹ ni wọn ṣe sa lọ raurau.
Adedeji ni ohun ti ko jẹ kawọn eeyan tete gbeja ko awọn janduku naa loju ni aṣọ ati imura wọn, wọn ti ri wọn nibi ti wọn ti duro lọdọ awọn imigireṣọn lakọọkọ ati nigba ti wọn fija pẹẹta pẹlu awọn imigireṣọn lẹẹkeji ro pe awọn onifayawọ kan ati awọn kọsitọọmu ni wọn n ja ni, eyi ni ko jẹ ki wọn tete fura.

Ọkunrin naa ṣalaye pe ori lo ko awọn eeyan ilu Igangan yọ, tawọn agbebọn naa fi ṣẹri pada, o ni ohun ti wọn ṣe lọjọsi naa ni wọn tun fẹẹ ṣe, pe wọn fẹẹ lugọ sitosi ilu naa lọwọ alẹ, ki wọn tun le ṣakọlu lọganjọ oru, ki wọn si tun paayan rẹpẹtẹ ni.

Tẹ o ba gbagbe, alẹ ọjọ Satide, ọjọ karun-un, oṣu kẹfa, si Sannde, ọjọ kẹfa, oṣu naa, lawọn Fulani agbebọn ya bo ilu Igbagan, ti wọn si pa awọn genge rẹpẹtẹ niluu naa nipakupa, bi wọn ti n yinbọn ni wọn fi ada ati aake ṣa ọpọ eeyan balẹ.

Nigba tilẹ yoo fi mọ, wọn ti dana sun ọpọ ile, ṣọọbu, ati aafin Aṣigangan tilu Igangan, ọpọ dukia ati okoowo awọn araalu naa ni wọn dana sun, titi kan awọn ọkọ ajagbe ti ko mọwọ mẹsẹ, to n kọja loru.

Gomina Ṣeyi Makinde ṣabẹwo siluu naa lati ba wọn kẹdun, o ni oun gba pe ẹbi oun niṣẹlẹ to waye ọhun, o si fi da wọn loju pe iyẹn lo maa jẹ igba ikẹyin tiru nnkan bẹẹ yoo tun ṣẹlẹ, ki ti ọjọ Ẹti yii too tun ṣẹlẹ.

Leave a Reply