Awọn Fulani agbebọn ya wọ abule Koka, nipinlẹ Ọṣun, eeyan mẹta ni wọn yinbọn fun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ana la gbọ pe awọn agbebọn kan, ti awọn to ri wọn sọ pe Fulani ni wọn, ya wọ abule Koka, nitosi Fasiti UNIOSUN, niluu Oṣogbo, pẹlu erongba lati ji awọn eeyan gbe nibẹ.

ALAROYE gbọ pe bi wọn ṣe debẹ ni wọn paṣẹ pe ki awọn eeyan maa to lọwọọwọ jade ninu ile wọn, ti wọn si n doju wọn kọ ọna inu igbo.

A gbọ pe ọkunrin kan lo dọgbọn bọ sinu okunkun, to si pe awọn ọlọdẹ (Hunters Group of Nigeria,) lati fi nnkan to n ṣẹlẹ to wọn leti.

Iwadii fi han pe awọn ọdẹ ti kẹẹfin awọn Fulani agbebọn yii tẹlẹ, ti wọn si ti n dọdẹ wọn kaakiri oju ọna Oṣogbo, titi de Imẹsi, ko too di pe wọn pada si Oṣogbo lalẹ ọjọ naa.

Kia ni wọn si mori le abule Koka lẹyin ti wọn gba ipe ọkunrin naa, ki wọn too debẹ, awọn Fulani yii ti ko awọn eeyan naa wọnu igbo, bẹẹ lawọn ọdẹ gba ya wọn.

Nigba to da bii ẹni pe agbara awọn Fulani naa pin ni wọn yinbọn fun mẹta lara awọn eeyan abule naa ti wọn n ko lọ, ti wọn si yọnda awọn to ku ki wọn too fẹsẹ fẹ ẹ.

A gbọ pe awọn mẹtẹẹta ti ibọn ba wa nileewosan kan bayii, nibi ti wọn ti n gba itọju, nigba ti awọn ọdẹ naa ko ti i dẹyin lẹyin awọn Fulani agbebọn ọhun ninu igbo ti wọn sa pamọ si.

Obinrin kan to ba wa sọrọ nibẹ, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri, sọ pe awọn Fulani agbebọn naa to mẹjọ pẹlu ibọn AK 47 lọwọ ikọọkan wọn. O ni mẹrin ninu wọn ni wọn wa sile oun, ti wọn si ko gbogbo awọn jade ninu ile.

Leave a Reply