Awọn Fulani agbebọn yinbọn pa pasitọ l’Akurẹ wọn tun ṣe awakọ rẹ leṣe

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Pasitọ ijọ CAC kan to wa lagbegbe Fasiti imọ-ẹrọ to wa l’Akurẹ,  Dokita Amos Arijesuyọ, lawọn Fulani agbebọn kan ti ṣeku pa, ti wọn si tun ṣe awakọ rẹ leṣe nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Pasitọ Olu Aladesanmi to jẹ ọkan lara awọn osisẹ abẹ rẹ pe iṣẹlẹ yii waye loju ọna marosẹ Ileṣa si Akurẹ lasiko ti wọn n bọ lati ilu Ibadan ni nnkan bii aago marun-un si mẹfa ọjọ naa.

O ni lojiji lawọn agbebọn ọhun bẹ ja ọna, ti wọn si ina ibọn bo ọkọ iranṣẹ Ọlọrun naa ati awakọ rẹ.

Awọn mejeeji lo ni wọn si wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun nigba ti wọn kọkọ gbe wọn de ileewosan kan niluu Akurẹ.

Alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lokiki kan lati ọọsi rẹ pe pasitọ yii ti ku nileewosan toun ati awakọ rẹ ti n gba itọju.

Pasitọ Aladesanmi ti rọ ijọba apapọ ati tipinlẹ lati tete wa nnkan ṣe lori ọrọ eto aabo to mẹhẹ lorilẹ-ede yii, ki wọn si tete gbe igbesẹ lori bawọn onisẹẹbi naa e n fojoojumọ fẹmi awọn alaisẹ ṣofo.

Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ Fasiti imọ-ẹrọ to wa l’Akurẹ (FUTA), ni Dokita Amos nigba to wa laye, wọn loun ni igbakeji ọga agba to n ri ṣeto igbaniwọle awọn akẹkọọ ko too jade laye.

Leave a Reply