Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Inu wahala nla lẹgbẹ awọn ti wọn n ṣeto ọgbin ati okoowo agbado, Maize Growers Processing Marketer Association of Nigeria (MAGPAMAN), wa nipinlẹ Ekiti bayii lẹyin tawọn darandaran kan ya bo oko wọn, ti wọn si jẹ agbado ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu.
Awọn agbado ọhun, eyi to wa lori ilẹ igba-le-marundinlogoji (235) eeka ni Aduloju, loju ọna Ijan-Ekiti si Ado-Ekiti, lẹgbẹ naa yawo lati gbin lopin ọdun to kọja.
Gẹgẹ bi Akọwe ẹgbẹ naa, Tọpẹ Emmanuel, ṣe ṣalaye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, o ni oru-ganjọ lawọn darandaran naa n wa si oko ọhun pẹlu nnkan ija oloro, lati bii ọsẹ kan sẹyin, bẹẹ awọn agbado ọhun ti too kore.
O ṣalaye pe ọdun to kọja ni ẹgbẹ naa ya miliọnu mẹfa ati ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta naira (N6.6m) lọwọ banki apapọ ilẹ yii lati gbin agbado, awọn ọmọ ẹgbẹ to si lọwọ si i jẹ ọgọjọ (160), bẹẹ lawọn n reti ere miliọnu mẹwaa, ṣugbọn ọrọ ti ba ọna mi-in yọ bayii.
Akọwe naa bẹ ijọba atawọn tọrọ kan lawujọ lati dide iranlọwọ fun ẹgbẹ naa, ki wọn si gba wọn silẹ lọwọ awọn darandaran apaayan yii.
O ni, ‘’Ẹ ma gbagbe pe ijọba lo ni ka lọọ maa dako, eyi lo jẹ ka lọọ ba banki apapọ, ti wọn si ya wa lowo, ka le san an pada lẹyin ta a ba ta awọn ere oko yẹn. Ni bayii, awọn darandaran ti da wahala si wa lọrun.
‘’A bẹ ijọba lati gba wa lọwọ gbese nla yii, nitori nnkan ti yoo ṣẹlẹ si wa ti a ko ba san an lagbara.’’
Lori igbesẹ tawọn ẹṣọ alaabo n gbe lori ọrọ naa, ẹgbẹ MAGPAMAN ni awọn ti fẹjọ sun awọn ọlọpaa ati ikọ Amọtẹkun, ṣugbọn wọn ko ṣe nnkan kan lori ẹ.
Nigba to n fesi si iṣẹlẹ ọhun, adari Amọtẹkun l’Ekiti, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, ni loootọ lawọn gbọ nipa ẹ, awọn si ti n gbe igbesẹ.