Awọn Fulani darandaran kọ lu agbẹ meji ninu oko l’Ẹrinle

Stephen Ajagbe, Ilorin

Awọn agbẹ meji; Joseph Goje ati Nathaniel Goje, ti wọn fi ilu Ọyan, nipinlẹ Ọṣun, ṣebugbe, ṣugbọn ti wọn n da oko labule Afọyin, niluu Ẹrinle, nipinlẹ Kwara, lawọn Fulani darandaran kan ṣe akọlu si lọjọ Abamẹta, Satidee, ọsẹ to kọja.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ lasiko tawọn mejeeji wa ninu oko wọn.

Iwadii fi han pe awọn darandaran naa ti wọn ko ju mẹta lọ, gbe ada ati igi lọwọ, wọn si dari awọn maaluu wọn wọlu oko agbado awọn agbẹ naa. Nigba tawọn yẹn fẹẹ ta ko wọn ni wọn fa ada yọ si wọn.

Bi wọn ṣe n ya bo awọn mejeeji niyẹn pẹlu igi ati ada ti wọn da bo wọn. Ṣugbọn ọkan lara awọn agbẹ naa mori bọ, oun lo sa lọ ke si awọn araalu, eyi lo mu kawọn darandaran naa sa lọ.

Iṣẹlẹ ọhun ti waa da ẹru sọkan awọn agbẹ naa bayii, wọn ni oko ko ṣee lọ mọ, nitori pe o ṣee ṣe kawọn darandaran naa tun pada waa ka wọn mọnu oko wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, ni wọn ko ti i fi iṣẹlẹ to awọn leti.

 

 

Leave a Reply