Awọn Fulani darandaran lo ji akẹkọọ yii gbe l’Eruwa, miliọnu kan lawọn ẹbi ẹ san ki wọn too ri i gba pada  

Faith Adebọla

Sọdirat Salami lorukọ ọmọbinrin yii, akẹkọọ ni nileewe Royal Institute of Health, ileewe aladaani kan ti wọn ti n kọṣẹ eto ilera lo ti n kawe kawọn Fulani darandaran too ji oun ati awọn meji mi-in gbe ninu ọkọ ti wọn wọ lọ siluu Eruwa lọjọ Wẹsidee ọsẹ yii. Amọ wọn ti fi ọmọbinrin naa silẹ nirọlẹ ọjọ keji, Ọjọbọ, Tọsidee yii, lẹyin tawọn ajinigbe naa gba miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba naira lọwọ awọn mọlẹbi ẹ.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni agbegbe kan naa tawọn Fulani agbebọn kan ti fibọn da ẹmi Alaaji Fatai Yusuf, ti gbogbo eeyan mọ si Ọkọ Oloyun, legbodo ni nnkan bii ọdun kan aabọ sẹyin niṣẹlẹ yii ti waye.

Wọn ni Sọdirat, to n ṣiṣẹ lọsibitu Olugbọn, niluu Igbo-Ọra, nijọba ibilẹ Aarin-Gbungbun Ibarapa, wọ ọkọ ayọkẹlẹ akero kan lati Igbo-Ọra lọ si Eruwa lẹyin to pari iṣẹ ọjọ naa, ki i si ṣoun nikan lọkọ naa gbe, awọn ọmọleewe OSCATECH, iyẹn Oyo State College of Agriculture and Technology meji mi-in wa ninu ọkọ ọhun, tawọn naa n lọ siluu Eruwa.

ALAROYE gbọ pe lojiji lawọn Fulani ajinigbe naa fo jana, ti wọn si fa ibọn yọ si mọto ti wọn wọ, bi dẹrẹba ọkọ naa ṣe duro pẹlu ibẹrubojo to ti mu oun atawọn ero inu ọkọ ọhun, bẹẹ lawọn agbebọn fipa wọ mẹta ninu wọn bọọlẹ, ni wọn ba ko wọn wọgbo lọ.

Alẹ ọjọ Wẹsidee naa lawọn olubi ajinigbe ẹda naa ti bẹrẹ si i kan sawọn mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe ọhun, oniruuru owo tabua ni wọn n bu pe ki wọn waa fawọn bi wọn ba fẹẹ ri ẹni wọn gba pada laaye.

Asẹyinwa-asẹyinbọ, a gbọ pe wọn papa gba owo ki wọn too fi Sọdirat silẹ, nigba tawọn meji ṣi wa lakata wọn di baa ṣe n sọ yii.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ti fiṣẹlẹ yii to ileeṣẹ ọlọpaa Eruwa leti ni teṣan wọn, a gbọ pe awọn ẹṣọ Amọtẹkun agbegbe Eruwa ti da sọrọ ọhun, awọn fijilante ibẹ naa si ti dide, wọn ti n wa ọna lati tu awọn to ku silẹ lakata awọn ajinigbe naa.

CAPTION

Leave a Reply