Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Egbinrin ọtẹ lọrọ awọn Fulani ti wọn n fẹsun ipaniyan kan lasiko yii, paapaa nipinlẹ Ogun, pẹlu bo ṣe jẹ pe niṣe ni wọn tun dumbu ọkunrin kan, Dele Olowoniyi, labule Ọha, n’Imẹkọ, ni nnkan bii aago kan oru ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
ALAROYE gbọ pe awọn Fulani naa de tijatija lọwọ oru, wọn si bẹrẹ si i yinbọn kaakiri. Bakan naa ni wọn ni wọn bẹrẹ si i ba awọn dukia awọn eeyan jẹ, lẹyin naa ni wọn wọle awọn Dele, wọn wọ ọ jade, wọn si fọbẹ si i lọrun, wọn dumbu rẹ bii ẹran.
Ohun to ṣẹlẹ yii lo jẹ kọpọ eeyan maa sọ pe nnkan mi-in wa ninu ọrọ awọn Fulani yii, wọn lo jọ pe awọn alagbara ninu ijọba n gbe lẹyin wọn lati maa fa wahala kiri nipinlẹ Ogun yii ni, nigba to jẹ wọn ti ni ẹnikẹni ko gbọdọ yọ wọn lẹnu.
Iṣẹlẹ iku Dele yii ka Ọmọọba Gboyega Nasir Isiaka(GNI) to dupo gomina lẹẹmẹta nipinlẹ Ogun lara pupọ, nitori ọmọ Imẹkọ ni ọkunrin naa.
GNI fibanujẹ sọrọ lori iku Dele, o ni awọn to waa dumbu ẹ yii ki i ṣe ọta Imẹkọ-Afọn lasan, ọta Naijiria ati ọta ọmọniyan lapapọ ni wọn.
‘‘Ọpọ ipaniyan bayii la ti foju ri kaakiri Naijiria, ni bayii wọn ti raaye wọ ilẹ Yoruba, ti wọn si ti n doju ija kọ awọn eeyan wa ni nilẹ Yewa, ko yẹ ki wọn fi awọn eeyan wa silẹ lati daabo bo bo ara wọn nigba ta a ni awọn agbofinro, ko si yẹ ki ẹmi awọn eeyan wa maa wa ninu idunkooko mọ ni ni gbogbo igba bayii.’’ Bẹẹ ni Ọmọọba Gboyega Isiaka wi.
Ẹ oo ranti pe lọsẹ to kọja yii ni ajafẹtọọ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ (Igboho) lọ si Egua, ọkan ninu awọn ilu ti wọn lawọn Fulani ti n da wọn laamu, ti wọn si ti sọ ara wọn di ẹru jẹjẹ mọ araalu lọwọ.
Ikọlu to n waye lawọn ilẹ Yewa yii ko ti i dawọ duro, eyi naa lo si fa a tawọn eeyan ibẹ fi tun n kegbajare pe kijọba ma jẹ kawọn di ajoji nilẹ baba awọn, nitori awọn Fulani to n fidan han awọn lojoojumọ yii.