Awọn Fulani ji tọkọ-tiyawo gbe l’Ẹsa-Oke, miliọnu mẹtadinlogoji naira ni wọn n beere bayii

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Tọkọti-yawo kan, London ati Blessing Omoru, ti wọn n gbe ni abule awọn agbẹ (Farm Settlement) to wa niluu Ẹsa-Oke. nipinlẹ Ọṣun, lawọn Fulani agbebọn ti ji gbe bayii.

ALAROYE gbọ pe ninu oko awọn tọkọ-tiyawo yii ni wọn ti ji wọn gbe nirọlẹ Ọjọruu, Wesidee, ọsẹ yii.

A gbọ pe lẹyin ti wọn ji awọn mejeeji gbe tan, inu igbo ni wọn gbe wọn lọ, ko si pẹ rara ti wọn fi ranṣẹ sawọn mọlẹbi wọn pe ki wọn wa miliọnu mẹtadinlogoji naira wa gẹgẹ bii owo itusilẹ.

Lẹyin ti awọn mọlẹbi Omoru gba ipe yii ni wọn lọọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa ilu Ẹsa-Oke leti.

A gbọ pe awọn ọlọpaa to n gbogun ti ijinigbe (Anti kidnapping), awọn ọlọdẹ, awọn figilante ati awọn ọmọ ẹgbẹ  Oodua Peoples Congress ti wa ninu igbo bayii lati gba awọn eeyan naa silẹ.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alakooso Kiriji Heritage Defenders, Dokita Ademọla Ẹkundayọ, ẹni ti awọn eeyan rẹ kọkọ bọ sinu igbo lati wa awọn tọkọ-taya naa, sọ pe awọn ajinigbe naa ko ti i din owo ti wọn n beere ọhun ku.

O ni awọn ti wọn wa ninu igbo n ṣiṣẹ takuntakun lọwọlọwọ lati gba awọn eeyan naa lai farapa.

Bakan naa ni Alukooro ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn agbofinro wa ninu igbo bayii, bẹẹ ni wọn si ti ri maṣinni ti awọn eeyan naa gbe lọ si oko.

Leave a Reply