Awọn Fulani ko maalu bii ẹgbẹrun kan wọ ilu Oṣogbo loru, awọn Amọtẹkun lo da wọn pada

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ṣe lawọn eeyan agbegbe Ọmọbọlanle, niluu Oṣogbo, atawọn awakọ ti wọn n kọja nibẹ lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, n sa kijokijo kaakiri nigba ti wọn deede ri maaluu ti wọn to ẹgbẹrun kan niye.

A gbọ pe bi awọn maaluu naa ṣe n lọ niwaju ni awọn Fulani darandaran ti wọn to mejila naa n bọ lẹyin wọn, idi si niyi ti awọn eeyan agbegbe naa fi tete fi ọrọ naa to awọn Amọtẹkun leti.

Wọn ni ko pẹ rara ti awọn Amọtẹkun de sibẹ lati ma ṣe jẹ ki awọn Fulani ọhun da awọn maaluu naa wọ aaringbungbun ilu.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alakooso Amọtẹkun l’Ọṣun, Amitolu Shittu, ṣalaye pe ootọ ni iṣẹlẹ naa, ati pe o da ipaya silẹ laarin awọn araalu nigba ti wọn ri wọn.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ootọ ni pe awọn Fulani darandaran kan ti wọn n bọ lati Ogbomọṣọ ko awọn maaluu ti wọn to ẹgbẹrun kan wọlu Oṣogbo laajin.

“Wọn kọkọ fẹẹ ba wa lo agidi, ṣugbọn nigba to ya, wọn duro. Wọn sọ pe omi lawọn n wa, ati pe awọn ti kọkọ lọ kaakiri ilu lọsan-an lati mọ ọna tawọn fẹẹ gba.

“A sọ fun wọn pe ko saaye kiko maaluu jẹko kaakiri nipinlẹ Ọṣun, bẹẹ ni ofin si ti wa to gbe e lẹsẹ. A dari wọn lọ sibi kan ti omi wa, lẹyin ti awọn maaluu wọn mumi tan la sin wọn jade kuro l’Ọṣun lọ si aala ipinlẹ kan lẹgbẹẹ wa.

“Ohun gbogbo ti bọ sipo bayii, ko si wahala.”

Leave a Reply