Awọn Fulani Kwara ni ẹgbẹ oṣelu PDP lawọn maa dibo fun lọjọ Satide

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gẹgẹ bii eto idibo apapọ ọdun 2023 ṣe n kan ilẹkun, ẹgbẹ awọn Fulani ni Kwara ti jẹjẹẹ atilẹyin wọn fun ẹgbẹ oṣelu PDP, wọn si ti ni oludije ẹgbẹ oṣelu naa to n dije dupo aarẹ lawọn yoo dibo fun ni Satide, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji yii.

Adari awọn Fulani niluu Lamba, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, Alaaji Usman Sule Jowuro-Lamba, lo sọrọ naa larukọ gbogbo awọn Fulani to wa niijọba ibilẹ mẹrẹẹrindinlogun nipinlẹ naa, lasiko ti wọn n ṣepade pẹlu Sẹnetọ Bukọla Saraki niluu Ilọrin.

Jowuro-Lamba ni yoo ti to bii aadọta ọdun sẹyin ti Fulani nipinlẹ Kwara ti n ṣe atilẹyin fun Olusọla Saraki to jẹ baba Bukọla Saraki to ti ku, fun idi eyi, gbọn-in gbọn-in ni awọn Fulani Kwara ṣi wa lẹyin ẹgbẹ oṣelu PDP, ti awọn yoo si maa tẹsiwaju lati maa ṣe atilẹyin fun wọn, wọn ni ki Bukọla Saraki lọọ fi ọkan balẹ.

Adari awọn Fulani niluu Ajasẹ-Ipo, tilu Oro, ati Alaaji Aliyu Mohammed Seriki Fulani ilu Bacita, nijọba ibilẹ Moro, nipinlẹ Kwara, ni wọn sọrọ larukọ awọn eeyan wọn, wọn ni gbogbo oludije dupo ninu ẹgbẹ oṣelu PDP lawọn yoo di gbogbo ibo awọn fun, bẹrẹ lati ori aarẹ to fi dori kansilọ, wọn ni awọn mọ iyatọ nigba ti Saraki wa lori oye si asiko ti awọn n lo lọwọ yii.

Olori ileegbimọ aṣofin Kwara tẹlẹ, Dokita Alli Ahmad, to ṣoju Saraki dupẹ lọwọ wọn, o si ni awọn yoo gbiyanju lati ri i pe ere oṣelu awa-ara-wa yoo ṣe kari gbogbo awọn Fulani naa.

Leave a Reply