Awọn Fulani ni kijọba mu Sunday Igboho, ki wọn si da Seriki pada s’Igangan

Latari lile ti wọn le Seriki Fulani, Alaaji Salihu AbdulKadir, kuro nilu Igangan, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, ti wọn si tun dana sun awọn dukia rẹ kan, ẹgbẹ awọn Fulani ilẹ Naijiria kan ti ke sijọba pe ayafi ti wọn ba fi pampẹ ofin mu Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, ti wọn si da Seriki Fulani ti wọn le naa pada siluu Igangan ni alaafia too le wa.

Ẹgbẹ awọn Fulani naa to fikalẹ siluu Abuja (Gan Allah Fulani Development Association of Nigeria) GADFAN, sọ ọrọ yii nigba ti wọn ṣabẹwo ibanikẹdun si Alaaji Salihu niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

Ẹgbẹ naa ni bi ijọba ko ṣe ti i fi pampẹ ọba mu Oloye Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, ki wọn si ba a ṣẹjọ, ko tẹ awọn lọrun rara.

Ninu atẹjade kan ti Alaga apapọ ẹgbẹ wọn, Alaaji Sulaiman Yakubu ati akọwe rẹ, Ibrahim Abdullahi, buwọ lu lorukọ ẹgbẹ ọhun lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, wọn ni ko yẹ ki Sunday Igboho ṣi wa lominira, ko maa yan fanda kiri ilu, tori awọn gbagbọ pe oun gan-an lo ṣagbatẹru akọlu ti wọn ṣe si Alaaji Salihu niluu Igangan lọjọsi.

Ẹgbẹ naa tun parọwa sijọba pe ki wọn fi pampẹ ofin gbe gbogbo awọn alatilẹyin Sunday Igboho, ati awọn ti wọn ba lọwọ ninu bi wọn ṣe dana sun awọn dukia Seriki Fulani ti wọn le jade niluu ọhun.

Lara ohun ti wọn tun beere pawọn fẹ kijọba ṣe ni pe ki wọn ṣeto bi Alaaji Salihu AbdulKadir yoo ṣe pada siluu Igangan, ki wọn pese aabo to peye fun un, ki wọn si san owo ‘gba ma binu’ fun un latari awọn dukia olowo iyebiye rẹ to padanu sinu iṣẹlẹ ọhun.

Atẹjade naa ka lapa kan pe: “Ẹgbẹ GADFAN n fi asiko yii ke sijọba apapọ ati ti ipinlẹ Ọyọ lati ri i pe wọn ṣe idajọ ododo fun Alaaji Saliju AbdulKadir ati awọn eeyan rẹ, ki i ṣe pe kijọba mu Sunday Igboho atawọn bọisi ẹ nikan ni, ṣugbọn ki wọn ba wọn ṣẹjọ, ki wọn si fiya jẹ wọn, lẹyin naa, ki wọn ri i pe wọn san owo to yẹ fun Seriki Fulani ati awọn eeyan rẹ, ki wọn si da wọn pada si ibi ti wọn ti n gbe tẹlẹ naa.

A ti kiyesi i pe akọlu ti wọn ṣe si Seriki Fulani nilu Igangan mu ko padanu ọpọlọpọ maaluu, ewurẹ, aguntan, ẹyẹ awo, ileewe aladaani rẹ kan, awọn ileetaja ati mọṣalaaṣi, aropọ eyi ti owo rẹ ju miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta naira (#500m) lọ.

Nipari atẹjade naa, wọn sọ pe awọn ti n ba awọn agbẹjọro awọn sọrọ, awọn si ti ṣetan lati gbe igbesẹ ofin tijọba ko ba tete dahun si awọn nnkan tawọn fẹ wọnyi.

Leave a Reply