Jide Alabi
Ninu ibanujẹ lawọn mọlẹbi ọkunrin oloṣelu kan, Dokita Fatai Aborode, wa bayii lori bi awọn eeyan kan ti wọn fura si gẹgẹ bii Fulani to n da ẹran ṣe kọ lu u lọna oko, ti wọn si ṣa a ladaa ni gbogbo ara, ti ẹmi ọkunrin naa si ti bọ bayii.
ALAROYE gbọ pe oko ni ọkunrin yii ti n bọ lọjọ Ẹti, Furaidee, pẹlu manija ẹ to n ba a mojuto oko ọhun labule Apodun, nipinle Ọyọ.
Deede aago mẹrin irọlẹ la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun waye, nigba ti wọn kuro loko ọhun, ti wọn si jọ gun ọkada kan naa, ni awọn janduku Fulani afurasi ọhun too kọ lu wọn niluu Igbo-Ọra.
Wọn ni lojiji ti wọn yọ si wọn ni manija ti raaye sa mọ wọn lọwọ, ṣugbọn ti Aborode ni tiẹ ko ri ibi kan sa lọ.
Ẹnikan to ba awọn oniroyin sọrọ, to pe ara ẹ ni Ṣeyi, so pe ọkan lara awọn oloṣelu to dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord Party, lati jẹ aṣoju-ṣofin fun awọn eeyan Igangan, Ibarapa, ni Fatai Aborode n ṣe lọdun 2015.
Wọn ni kaakiri orikeerikee ara ẹ lawọn janduku ọhun ti ṣa a ladaa, eyi to mu Aborode gbẹmi mi ki wọn too gbe e de ileewosan kan ti wọn n pe ni Olugbọn Hospital.
Pẹlu gbogbo akitiyan lati gbọ tẹnu agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa lori iṣẹlẹ yii, Ọgbeni Olugbenga Fadeyi ko ti i sọ ohunkohun, bẹẹ ni ko ti i si akọsilẹ kankan pe wọn ti mu ẹnikẹni bayii lori iṣẹlẹ ọhun, iyẹn lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.