Awọn Fulani pa agbẹ meji sinu oko n’Isaba-Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Wahala mi-in tun ti bẹ silẹ niluu Isaba-Ekiti, nijọba ibilẹ Ikọle bayii, pẹlu bi awọn kan ti wọn fura si bii Fulani darandaran ṣe pa awọn agbẹ meji sinu oko.

Awọn oloogbe naa la gbọ pe ọkan ninu wọn n je Jisoro gẹgẹ bii inagijẹ, nigba ti ekeji jẹ ẹṣọ alaabo ileeṣẹ kan.

Alẹ Ọjọ Ẹti, Furaidee, la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ lẹyin ti awọn agbẹ naa ṣe ni gbolohun asọ pẹlu awọn Fulani darandaran, eyi to pada ja si iṣekupani.

Lẹyin tawọn eeyan naa ṣiṣẹ laabi ọhun tan ni wọn sa lọ.

Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, ṣalaye pe ija lo waye laarin awọn eeyan naa, awọn darandaran wọnyi ni wọn si fẹsun kan pe wọn n da agbegbe Ipaọ, Oke-Ako ati Irele laamu.

O waa ni oku awọn oloogbe ti wa ni mọṣuari, bẹẹ ni awọn ọlọpaa ti wa ni agbegbe ọhun, iwadii si ti bẹrẹ.

Adari ikọ Amọtẹkun l’Ekiti, Ọgagun-fẹyinti Joe Kọmọlafẹ, sọ pe ọjọ Ẹti lawọn oloogbe dawati, eyi lo si fa ibẹru fawọn eeyan agbegbe ọhun.

O ni kia ni ikọ Amọtẹkun atawọn ọlọpaa ti lọ sibẹ, ibẹ lawọn si ti ba awọn oku naa.

Kọmọlafẹ ni iwadii fi han pe awọn Bororo to fẹẹ ko oyin ninu oko awọn oloogbe lo da wahala silẹ, iyẹn ni bii ọjọ meji si asiko naa, awọn lo si pada waa yinbọn pa wọn.

ALAROYE gbọ pe awọn eeyan ilu naa ti bẹrẹ ifẹhonuhan nitori iṣekupani ti wọn ni o ti n di gbogbo igba naa.

Leave a Reply