Awọn Fulani tan alapata mẹrin wọnu igbo l’Akurẹ, wọn pa awọn meji, wọn tun ji ọga wọn gbe lọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn gende ọkunrin meji pade iku ojiji nigba ti ẹni kẹta wọn si tun fara gbọgbẹ yannayanna nibi tawọn Fulani darandaran kan ti n gbiyanju ati ji ọga awọn alapata kan gbe niluu Akurẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ni nnkan bii aago kan ọsan ni Fulani kan pe ọga awọn alapata ọhun sori ago, to si ni ko tete maa bọ si agbegbe Ajadusi, Ala, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, lati waa ra maaluu.
Bi oun atawọn ọmọọsẹ rẹ mẹta ti de agbegbe naa lawọn Fulani ti yí wọn ka, ti wọn si n yinbọn soke kikan kikan.
Nibi tawọn mẹtẹẹta to tẹle ọga wọn lọ soko maaluu rira ti n wọna ati sa lọ lawọn ajinigbe naa ti sa meji ninu wọn ladaa pa, ṣugbọn ti ori ko ẹni kẹta wọn yọ.
Eyi ni alaye diẹ ti ọmọkunrin ọhun to porukọ ara rẹ ni Nasiru Jamiu ṣe fawọn oniroyin nile-iwosan kan to ti n gba itọju lọwọ.
”Awọn Fulani to maa n ta maaluu fun ọga wa lo pe wọn sori aago lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ti wọn si ni ki wọn maa bọ lati waa ra awọn maaluu kan ti awọn ti ṣeto silẹ de wọn.
Awọn Fulani ọhun ko ṣẹṣẹ maa taja fun ọga wa, ọjọ pẹ ti wọn ti jọ n ba ara wọn raja.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, la kọkọ fẹẹ lọ, ṣugbọn ba a ṣe n lọ loju ọna ni ọga wa ni ka pada sile, wọn ni ọkan awọn ko fẹẹ tẹsiwaju lọ sibi ta a n lọ mọ.
Fulani to n pe wọn ko jẹ ki wọn sinmi, ṣe lo n pe wọn ṣaa ni gbogbo igba, to si n fi wọn lọkan balẹ pe ki wọn tete yọju si oun ki awọn le jọ sọ asọye ọrọ lori awọn ọja ti oun fẹẹ ta wọn.
Nigba ta a pe wọn lọjọ Aje, Mọnde, wọn ni ka maa bọ, ati pe awọn ti ran awọn eeyan kan kí wọn waa duro de wa ni ilu Ala lati mu wa lọ sibi tawọn maaluu ta a fẹẹ ra wa.
”Ko pẹ ta a fi kuro ni Ala ta a sì tun tẹsiwaju ninu irinajo wa, nigba ta a de ibikan, wọn ni ka da ọkọ wa duro ki awọn le ko awọn maaluu ọhun jade ninu igbo ti awọn ko wọn pamọ sì.
”Dipo awọn maaluu ta a n reti, iro ibọn la bẹrẹ si i gbọ leralera ni ayika wa, ka si too mọ ohun to n sẹlẹ, awọn Fulani ti ki ọga wa mọlẹ, wọn sì ji wọn gbe wọnu igbo lọ.
”Ibi tawa ọmọọsẹ rẹ mẹta ta a tẹle e lọ ti n wọna ati sa asala fun ẹmi wa ni wọn ti ya bo wa, ti wọn si n ṣa wa ladaa kíkan kikan.
”Nigba ti mo ṣakiyesi pe ṣe ni wọn kuku fẹẹ pa mi ni mo dibọn bii ẹni pe mo ti ku, eyi lo jẹ ki wọn fi mi silẹ ti awọn naa si sa wọnu igbo lọ.
Lẹyin ti mo rọra laju diẹ ti mo rí i pe wọn ko si nitosi mọ ni mo sare dide ti mo si sa kuro nibẹ.
Ọga wa nikan ni wọn ji gbe loju mi, mi o le sọ ni pato ohun to sẹlẹ sawọn ẹlegbẹ mi meji ta a jọ tẹle wọn lọ, boya ṣe ni wọn ti ji awọn naa gbe.”
Ohun ta a gbọ ni pe awọn ẹsọ alaabo ti ri oku awọn ọmọọsẹ alapata mejeeji nibi tawọn Fulani ajinigbe ọhun wọ wọn ju si.
Bakan naa la gbọ pe wọn ti kan sawọn ẹbi ọga wọn ti wọn ji gbe, ti wọn si n beere ọgọrun-un miliọnu Naira lọwọ wọn.

 

Leave a Reply