Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Pupọ awọn eeyan ipinlẹ Ondo ni wọn fẹrẹ gba ilu, ki wọn maa jo kaakiri, nigba ti wọn gbọ pe Gomina Rotimi Akeredolu buwọ lu ofin to ta ko kiko ẹran jẹ nita gbangba lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹsan-an, ọdun ta a wa yii.
Gbogbo awọn ti wọn gbọ nipa iroyin ọhun nigba naa ni wọn n kan saara si Arakunrin lai fi ti ẹgbẹ oṣelu ti wọn wa ṣe, ti wọn loun gan-an lawọn ri gẹgẹ bii onigboya ati olugbala to ṣetan lati gba awọn eeyan silẹ ninu ajaga awọn Fulani darandaran to n ṣe wọn bii ọsẹ tii ṣoju.
Awọn ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo naa ko si fọrọ ọhun falẹ rara pẹlu bi wọn ṣe fi pampẹ ofin gbe awọn Fulani darandaran kan pẹlu ọpọlọpọ maaluu ti wọn n da lori ẹsun titapa si ofin ikẹran-jẹko tijọba sẹsẹ buwọ lu.
Ohun ti alakooso wọn, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, si n tẹnu mọ ni kete tọwọ ba ti tẹ awọn arufin ọhun ni pe ko sọna ti wọn yoo gbe e gba ti wọn ko ni i foju bale-ẹjọ lati lọọ gba ijiya to tọ fun bi wọn ṣe ṣaigbọran sofin ijọba.
Ohun to n ṣe awọn eeyan ipinlẹ Ondo ni kayeefi lọwọlọwọ ni bi ijọba atawọn agbofinro ṣe kọ lati tẹsiwaju ninu ifẹsẹmulẹ aba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ sọ dofin ọhun laarin oṣu kan pere ti wọn ni awọn ti bẹrẹ rẹ.
Awọn bororo darandaran tun ti bẹrẹ isẹ ẹran dida wọn laarin gbungbun ilu lakọtun lai si ibẹru pe boya ẹnikẹni le waa mu awọn.
Ninu iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ lati agbegbe Akoko to jẹ ẹkun Ariwa ipinlẹ Ondo, eniyan mẹta ni wọn lori ko yọ lọwọ iku airotẹlẹ loju ọna Afin si Oke-Agbe Akoko lọsẹ to kọja pẹlu bawọn maaluu kan ṣe deedee jana mọ ọkada wọn lẹnu lojiji laarin igboro ilu Afin.
Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ku ninu awọn mẹtẹẹta to wa lori ọkada naa, sibẹ, gbogbo wọn ni wọn fara pa yannayanna, ọpọlọpọ ọjọ ni wọn si fi wa nile-iwosan ki wọn too bẹrẹ si i gbadun diẹdiẹ.
Kiakia lawọn Fulani to n da awọn maaluu naa ti ba ẹsẹ wọn sọrọ, ti wọn si sa lọ tefetefe kawọn ẹṣọ Amọtẹkun ti wọn ranṣẹ pe too de sibi iṣẹlẹ ọhun, oku maaluu kan ti wọn kọ lu pẹlu ọkada to ti run womuwomu nikan ni wọn ri gbe lọ si ọfiisi wọn.
Ọsẹ yii kan naa lawọn eeyan ilu Ọgbẹṣẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, lẹkun Aarin Gbungbun ipinlẹ Ondo, ko ara wọn jọ siwaju aafin Ọlọgbẹsẹ lati fẹhonu han ta ko bawọn darandaran ṣe kọ lati jawọ ninu fífi maaluu ti wọn n sin ba ire oko wọn jẹ.
Awọn olufẹhonu han ọhun ni ko si iṣẹ mi-in tawọn tun n ṣe lagbegbe naa to ju iṣẹ agbẹ lọ, ṣugbọn to jẹ pe bo ti wu kawọn ṣiṣẹ karakara to, awọn Fulani ki i jẹ kawọn rohunkohun mu wale gẹgẹ bii ire oko.
Wọn ni ṣe lawọn darandaran agbegbe naa n ṣe bo ṣe wu wọn, ti ofin ikẹran-jẹko tijọba Akeredolu buwọ lu ko si di wọn lọwọ lati ko maaluu wọn lọ sibikibi to ba wu wọn.
Ohun tawọn araalu si fẹnu ko le lori ni pe o ṣee ṣe kawọn ma duro de iranlọwọ lati ọdọ ijọba mọ, wọn ni awọn ti ṣetan ati maa daabo bo, tabi gbeja ara awọn, tijọba ba fi kuna ati gbe igbesẹ to yẹ lasiko.
Bakan naa lọmọ ṣori niluu Akurẹ to jẹ olu ilu ipinlẹ Ondo, igba to ba wu awọn Fulani wọnyi ni wọn n ko ẹran wọn jade, ibi to ba si wu wọn ni wọn n ko o lọ pẹlu lai si ẹni ti yoo di wọn lọwọ.
Ẹnikan to ba wa sọrọ niluu Ondo ti i ṣe ibujokoo ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ni awọn darandaran wọnyi ki i jẹ kawọn o sinmi lawọn agbegbe bii, Ayeyẹmi, Ebenezery, Cele, Oke-Bọla ati Abayọmi.
O ni igba gbogbo ni wọn n daran kaakiri gbogbo agbegbe naa laibikita boya ofin de awọn tabi bẹẹ kọ.
Yatọ si ọrọ riru ofin ikẹran-jẹko ita gbangba eyi to ti di baraku lagbegbe Ayeyẹmi, awọn Fulani ọhun lo ni wọn tun kọ lati tẹle ofin to de awọn ọmọde wọn lati maa nikan daran jẹ.
Ọpọlọpọ awọn Fulani to n daran lawọn agbegbe wọnyi lo ni wọn ki i ju bii ọmọ ọdun mẹwaa si mejila pere lọ.
A gbiyanju lati ba Oloye Adetunji Adelẹyẹ to jẹ alakooso ẹsọ Amọtẹkun l’Ondo sọrọ lati fidi awọn iṣẹlẹ wọnyi mulẹ, ṣugbọn a ko ri esi atẹjiṣẹ ta a fi ṣọwọ si i titi di asiko ta a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ.