Awọn Fulani darandaran ra fọọmu fun Goodluck Jonathan, wọn ni koun naa waa dupo aarẹ APC

Jọkẹ Amọri

Aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Dokita Goodluck Jonathan, naa yoo kopa ninu ibo abẹle ẹgbẹ APC ti yoo waye nipari oṣu yii pẹlu bi awọn Fulani, Almajiri atawọn eeyan wọn ṣe ko ara wọn jọ, ti wọn dawo, ti wọn si ra fọọmu fun ọkunrin naa pe koun naa waa dije.
Alaroye gbọ pe awọn eeyan naa ni wọn gba International Conference Centre, Abuja lọ, ti wọn si gba fọọmu fun gomina ipinlẹ Bayelsa tẹlẹ, to tun figba kan jẹ aarẹ ilẹ wa pẹlu miliọnu lọna ọgọrun-un Naira.
Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin naa ko ti i kede nibikibi pe oun fi ẹgbẹ PDP silẹ lati darapọ mọ APC, sibẹ, ọkunrin yii ti gba fọọmu lati dije lorukọ ẹgbẹ APC ninu ibo aarẹ to n bọ.

Leave a Reply