Awọn Fulani to ji ọba gbe l’Ekiti ti wa lahaamọ

 Taofeek SurdiqAdo-Ekiti

 Ile-ẹjọ Majisitreeti kan to fi ilu Ado-Ekiti ṣe ibujokoo ti paṣẹ pe kawọn Fulani meji kan, Abdulameen Lawal; ẹni aadọta ọdun ati Bello Mohammad; ẹni ọdun marundinlogoji, lọọ maa gbatẹgun lẹwọn Ado-Ekiti na, nitori Ọba David Oyewumi ti ilu Ilemeso-Ekiti, nijọba ibilẹ Ọyẹ, ti wọn ji gbe loṣu kẹrin, ọdun 2021.

Agbẹnusọ ijọba, Inspẹkitọ Bamikọle Ọlasunkanmi, ṣapejuwe ijinigbe ti wọn n jẹjọ ẹ yii bii ohun to lodi sofin.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Mohammad Salau, paṣẹ pe kawọn mejeeji ṣi wa lẹwọn titi di ọjọ kẹrinla, oṣu keje, yii ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹrin, ọdun yii, ni awọn agbebọn kan ṣadeede dabọn bolẹ, lẹyin ti wọn fọ ogiri aafin Kabiyesi Oyewumi wọle.

Lọgan ti wọn wọnu aafin ni wọn di kabiyesi lọwọ mu, ti wọn bẹrẹ si i na an. Wọn gbe ọba alaye naa sori ọkada, bi wọn ṣe lọ ti ẹnikẹni ko mọ ibi ti wọn gbe ọba lọ niyẹn.

Ko too di pe ọwo palaba wọn ṣegi ti wọn dero ahamọ.

Leave a Reply