Awọn Fulani to ji ọmọ Ẹsin-o-gba-mi-laye n’Ilọrin beere fun miliọnu lọna ọgbọn naira

Aderohunmu Kazeem

Wahala nla ni awọn Fulani ti wọn ji ọmọ gbajumọ olorin Musulumi, Mumeen Damilọla, tubọ ko o si bayii pẹlu bi wọn ṣe ni ko lọọ wa ọgbọn miliọnu naira wa to ba ṣi fẹẹ ri ọmọ ẹ laaye.

Ori ikaani ayelujara wasaapu lọkunrin olorin ti awọn eeyan tun mọ si Ẹsin-o-gba-mi-laye yii gba lọ lọwọ aṣaalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ẹbẹ to si n bẹ gbogbo ọmọ Naijiria ni pe ki wọn ran oun lọwọ, ki oun le ri ọmọkunrin oun, Abdul-Basit, gba pada lọwọ awọn ajinigbe yii.

Fidio mi-in tawọn eeyan tun ri ni ti iyawọ ẹ, Mujidat Damilọla, toun naa jẹ olorin Islam, ẹbẹ loun naa n bẹ gbogbo ọmọ Naijiria, ki wọn ran awọn lọwọ lori bi ọmọ ọhun yoo ṣe pada sile. Bẹẹ lo fi kun un pe oun loun tọ ọmọ naa lati kekere, ati pe Basit paapaa ko tete mọ pe oun kọ niya ẹ, nitori o kere pupọ nigba toun fẹ baba ẹ.

Aṣaalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, ni awọn janduku Fulani bii mẹrin kan kọlu ile aburo ẹ ni Gaa Saka, lẹgbẹẹ Adewọle, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, nibi ti wọn ti pa iyawo aburo ẹ yii pẹlu oyun ibeji ninu, ki wọn too tun gbe ọmọ ẹ, Abdul-Basit Damilọla to jẹ ọmọleewe Kwara Poli lọ.

One thought on “Awọn Fulani to ji ọmọ Ẹsin-o-gba-mi-laye n’Ilọrin beere fun miliọnu lọna ọgbọn naira

Leave a Reply