Awọn Fulani tun ṣọṣẹ ni Ṣaki, eeyan mẹta ni wọn ṣa yanna-yanna lọna oko wọn

Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun

Afi bii ẹfọ gbọọrọ, ti Yoruba n powe pe ọrọ ko dun gbọọrọ, bi a fẹ ẹ laaarọ, aa ru lalẹ, bẹẹ lọrọ awọn Fulani darandaran lagbegbe Oke-Ogun, nipinlẹ Ọyọ yii, eeyan mẹfa ti wọn n dari bọ lati oko wọn jẹẹjẹ lawọn Fulani yii rẹbuu lopin ọsẹ to kọja yii, wọn gbowo ati foonu ọwọ wọn, wọn si fada ṣa mẹta lara wọn bii maaluu tawọn alapata fẹẹ kun.

Ọkunrin to to wa lara awọn to kagbako akọlu ọhun, Ọgbẹni Idowu Adetunji ba akọroyin ALAROYE sọrọ nibi to ti n gba itọju, o ṣalaye pe deedee aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, niṣẹlẹ naa waye, o lọna Ṣaki si ilu Agbọnle, nidojukọ oke Aṣubiojo ,ti ko ju kilomita meje siluu naa lo ti ṣẹlẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni gbara toun yọ si wọn lori alupupu Bajaj toun n gun bọ ni wọn da oun duro, ti wọn si n fi ede Hausa beere owo lọwọ oun. O ni wọn n pariwo pe ‘kao kudi, kao kudi,’ to tumọ si ‘owo da, owo nkọ’ lede Hausa.

O ni bi wọn ṣe n beere yii ni wọn n fi kumọ ati ada lu oun, oun si bẹ wọn, oun ṣalaye fun wọn pe oko loun ti n bọ, ki i ṣe ibi iṣẹ owo, ko si sowo kan lọwọ oun ju iwọnba ṣenji toun fi sapo lọ, sibẹ ọrọ oun ko ta leti wọn, wọn lu oun titi toun fi daku mọ wọn lọwọ, o lawọn kan tun sọ oun lokuta pẹlu.

Ọgbẹni Adetunji ti gbogbo eeyan mọ si Jimọh Katakata lati ọdun 2017 toun ti fẹyinti lẹnu iṣẹ ọfiisi loun ti n ṣiṣẹ agbẹ igbalode, toun si da oko ọgbin agbado, ọka baba, paki ati ẹwa Soya sagbegbe naa.

O ni lẹyin tawọn Fulani naa lu oun tẹrun, diẹ lo ku ki wọn pa oun lẹyin ti wọn ti gba dukia oun tan. O lọkunrin mi-in toun naa ko si wọn lọwọ nibẹ, ṣugbọn to ba wọn ṣagidi, niṣe ni wọn fada ge ọwọ rẹ kan ki wọn too na papa bora, wọn si tun gbe ọka Bajaj oun sa lọ.

O lọpẹlọpẹ awọn to n kọja lọ lẹyin asiko naa ni wọn ba oun nibi toun ti n pọkaka iku ki wọn too gbe awọn lọ sileewosan Muslim Hospital, to wa niluu naa fun itoju.

O loun ti lọọ fi iṣẹlẹ naa to aṣaaju awọn ọlọdẹ agbegbe naa, Pa Samson Ojoawo, ati Ọkẹrẹ ilu Ṣaki, Ọba Khalid Ọlabisi, leti, bẹẹ loun si jẹ ki ọga ọlọpaa agbegbe naa, SUPO Toyin Eniṣẹyin mọ si iṣẹlẹ ọhun, tori yatọ si toun, awọn eeyan meji mi-in ni wọn tun ṣakọlu si lalẹ ọjọ ọhun.

O ni wọn ṣeleri foun lati ṣewadii, ati pe awọn yoo ba oun wa ọkada oun ti wọn ji gbe lọ.

Adetunji ni nibi tọrọ de yii, ko sigba tawọn eeyan ko ni i maa gbeja ara wọn, ti wọn yoo si maa fi iṣọ ṣọ ara wọn funra wọn.

Leave a Reply