Awọn Fulani ya wọ Ajọwa Akoko, lawọn araalu ba n sa kijokijo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Asiko ta a wa yii ko fi bẹẹ dẹrun rara fawọn eeyan ilu Ajọwa Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Iwọ-Oorun Akoko, latari bi ọgọọrọ awọn Fulani kan ṣe deedee ya wọlu ọhun lọsẹ to kọja lai gba aṣẹ lọwọ ẹnikẹni.

Agba ilu naa to ba ALAROYE sọrọ ṣalaye pe ẹnikan to ri awọn Fulani darandaran ọhun loru ọjọ ti wọn wọlu pẹlu ọkọ ajagbe mẹta to ko wọn wa lo sare waa sọ fawọn eeyan.

O ni iroyin yii lo mu kawọn ọdẹ, fijilante atawọn araalu kan to gboya gbera lati lọọ fidi iroyin ti wọn gbọ naa mulẹ boya loootọ lawọn boroboro ọhun wa ninu igbo ti wọn ti ri wọn.

Alagba yii ni ṣe ni jinnijinni bo ọpọ awọn to lọ, ti awọn mi-in si fẹrẹ le tọ si sokoto nigba ti wọn kan awọn Fulani ọhun ti wọn pọ bii eesu ninu igbo Uro, ti wọn fi ṣe ibugbe.

O ni kayefi nla lo jẹ fun awọn pẹlu bawọn darandaran Ajọwa ṣe kọ lati tẹle aṣẹ ijọba to ni ki wọn kuro ninu igbo ọba, dida ẹran jẹ nita gbangba ati kiko maaluu fawọn ọmọde lati maa da kiri.

Meji ninu awọn aṣaaju ọdẹ ilu Ajọwa, Ọgbẹni Sọji Ogedemgbe ati Audu Badru, sọ pe ọrọ awọn Fulani ọhun ti dẹrujẹjẹ sawọn araalu lọrun.

Wọn ni iṣẹlẹ agbẹ kan ti wọn ṣa pa mọ inu oko rẹ ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin ko ti i tan lara awọn.

Awọn mejeeji ni Ojo lawọn fura si pe o fẹẹ gbabọde fawọn araalu, wọn ni iwadii awọn fidi rẹ mulẹ pe oun lo fun awọn Fulani ọhun laṣẹ ki wọn waa sọ agbegbe Ajọwa di ibugbe.

Ohun ta a gbọ ni pe wọn ti fun awọn Fulani ọhun ni gbedeke ọjọ ti wọn gbọdọ kuro nibi ti wọn tẹdo si naa.

Leave a Reply