Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ọjọ mẹta ti awọn agbofinro ilẹ Yoruba, Amọtẹkun ẹka ipinlẹ Ọyọ, ti lọọ gbéjà ka awọn afurasi ajinigbe mọ ibuba wọn ninu aginjù igbo, ti wọn sì yinbọn pa mẹta ninu awọn agbesunmọmi náà lẹyìn ija alagbara to waye laarin wọn, awọn Fulani ti dihamọra ija wọ ipinlẹ Ọyọ, wọn ni wọn fẹẹ gbẹsan pipa tàwọn agbofinro pa ninu wọn lọjọsi ni.
Orugànjọ́ lawọn eeṣin-ò-kọ-kú ẹda naa fi boju wa. Loru ọjọ Abamẹta, Sátidé, mọju ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni wọn ya wọ ipinlẹ Ọyọ tibọn-tibọn.
Ọkan ninu awọn olugbe ilu Idere, lagbegbe Ìbàràpá, to fìdí iṣẹlẹ yii mulẹ woye pé ẹsan pipa ti awọn Amọtẹkun pa ninu wọn lasiko ija to waye nigba ti awọn agbofinro wa wọn lọ sinu aginjù igbo ti wọn n lo fún iṣẹ laabi won, lawọn afurasi agbesunmọmi náà fẹẹ gba ti won fi ṣigun wọ ipinlẹ yìí.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ọkọ bọọsi nla meji to kún fun awọn Fulani bíi ogoji (40) lawọn Amọtẹkun, Operation Burst atawọn ọdẹ ri lagbegbe Ibarapa loru mọju ọjọ Sannde.
“Fulani ni gbogbo wọn, gbogbo wọn ni wọn dihamọra pẹlu nnkan ìjà bii ibọn, àdá, idà ati oríṣìíríṣìí nnkan ìjà oloro.
“Agọ ọlọpaa to wa niluu Eruwa lawọn agbofinro gbe wọn lọ. Lẹyin naa lawọn alaga kansu agbegbe Ibarapa wọn panu pọ fọwọ si i pe kí won gbe awọn eeyan wonyi lọ sileeṣẹ ọlọpaa n’Ibadan.”
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi, fidi iroyin yii múlẹ, o ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.
Sugbon nigba ti akọroyin wa pe agbẹnusọ fún ẹṣọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ lati fìdí iṣẹlẹ yii mulẹ siwjau, obinrin naa, Abilekọ Ayọọla Adedọja, sọ pe oun yóò pe pada nitori oun n wa mọto lọwọ, ṣugbọn lẹyin wakati meji sigba naa ti akọroyin wa tun pe é, ko gbe awọn ipe naa titi ta a fi kọ iroyin yii tan.