Awọn Fulani ya wọlu Igangan loru, wọn paayan, wọn tun dana sunle rẹpẹtẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn ara ilu Igangan lagbegbe Oke-Ogun ni ipinlẹ Ọyọ ko le sun mọju oni fun ibẹru ofo ẹmi ati dukia wọn pẹlu bi awọn Fulani ṣe ya lu wọn ninu ilu naa ti wọn si dana sun ile rẹpẹtẹ.

Wọn gbẹmi awọn eeyan ninu ikọlu ọhun o: awọn eeyan rẹpẹtẹ

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, lọganjọ oru ọhun naa lawọn ọlọpaa, fijilante atawọn Amọtẹkun agbegbe Igangan ti ta mọra lati lọọ koju awọn ọdaran naa. Bo Si tilẹ jẹ pe igbesẹ yii lo ṣi awọn ọdaju eeyan wọnyi lọwọ iwa ọdaran naa, awọn agbofinro ko tii ri ọkankan ninu wọn mu nitori bi wọn se gburoo awọn agbofinro ni wọn ti na papa bora.

Ọmọ ilu Igangan kan ti ko fẹ ka darukọ oun sọ pe “Ni nnkan bíi aago kan oru ni wọn ya wọlu ti wọn si bẹrẹ si i dana sunle awọn eeyan kiri.

“Awọn Fulani ni wọn ṣiṣẹ buruku yẹn. Boya nitori kikuro ti ọga wọn, Iskilu Wakilu kuro nilẹ yii ni wọn ṣe n kanra bẹẹ.”

Ta o ba gbagbe, lọjọ kejilelogun (22) oṣu kin-in-ni ọdun 2021 yii lolori awọn Fulani naa sa kuro niluu Igangan latari bi ajafẹtọọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ (Sunday Igboho), ṣe kilọ fawọn to n huwa ọdaran laarin awọn Fulani agbegbe Oke-Ogun lati fi agbegbe naa silẹ bi wọn ko ba fẹ ki oun kogun ja wọn.

Akitiyan wa lati fìdí iroyin yii mulẹ lẹnu awọn agbofinro ko seso rere pẹlu bi alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, DSP Adewale Ọṣifẹṣọ, ko ṣe gbe ipe akọroyin wa, ti Abilekọ Ayọlọla Adedọja to jẹ agbẹnusọ ajọ Amọtẹkun ti i ṣe ikọ eleto aabo ipinlẹ Ọyọ si sọ pe oun ko tii gbọ nipa iṣẹlẹ naa.

Titi ta afi pari akojọ iroyin yii, a ko tii ri ipe Abilekọ Adedọja gẹgẹ bíi ileri to ṣe fakọroyin yii.

Leave a Reply