Awọn gomina Guusu tun ṣepade: Ijọba ipinlẹ ni yoo maa gbowo-ori VAT

Faith Adebọla, Eko

Awọn gomina mẹtadinlogun ti ipinlẹ Guusu orileede wa ti kede pe gbọin-gbọin lawọn wa lẹyin ki ijọba ipinlẹ maa gba owo-ori ọja ti wọn n pe ni VAT, wọn ni kawọn ipinlẹ gba eto naa kuro lọwọ ijọba apapọ ati ileeṣẹ agbowoori wọn, FIRS.

Ọrọ yii jade ninu atẹjade ti Alaga awọn gomina ipinlẹ Guusu, to tun jẹ Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu, ka jade lẹyin ipade wọn to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nileejọba ipinlẹ Enugu, niluu Enugu.

Awọn gomina naa lawọn ti panu-pọ pe abẹ aṣẹ ijọba ipinlẹ ni gbigba owo-ori VAT wa, wọn ni bo ṣe wa ninu iwe ofin ilẹ wa tọdun 1999 ti a n lo niyẹn, tori naa, awọn fara mọ bawọn ipinlẹ ṣe bẹrẹ si i ṣofin lati maa gba owo-ori naa labẹle wọn.

Yatọ si ọrọ owo-ori VAT, awọn gomina naa tun sọ pe ipinnu tawọn ti ṣe tẹlẹ pe ki ipo aarẹ ninu eto idibo to n bọ wa si iha Guusu ilẹ wa ko yipada, wọn ni Guusu ni aarẹ ti gbọdọ yọju.

Bakan naa lawọn gomina ọhun gboṣuba fun bawọn ipinlẹ Guusu ṣe fọwọsowọpọ lori ofin ta ko fifẹranjẹko ni gbangba kaakiri awọn ipinlẹ wọn, wọn ni inu awọn dun si iṣẹ tawọn aṣofin ipinlẹ kọọkan ṣe, wọn si parọwa sawọn ipinlẹ to ku lati ṣiṣẹ lori ofin naa, tori ki alaafia ati aabo le rẹsẹ walẹ ni Guusu orileede wa.

Leave a Reply