Awọn gomina ilẹ Hausa ni awọn ọdọ fẹẹ fi iwọde SARS le Buhari kuro nile ijọba ni

Aderohunmu Kazeem

Nipinlẹ Kaduna, lawọn gomina ilẹ Hausa pe ipade kan si ni ọjọ Aje, Mọnde, ọse yii, nibi ti wọn ti ṣepade lori awọn ohun to n lọ nilẹ wa, ti wọn si fẹnu ko sawọn koko pataki kan.

Simon Lalong, eni ti i ṣe gomina ipinlẹ Plateau, ni alaga awọn gomina ilẹ Hausa, oun naa lo si dari ipade ọhun to waye ni Sir Kashim Ibrahim House, ni Kaduna.

Wọn dupẹ lọwọ awọn ọba alaye atawọn olori esin gbogbo lori isẹ takuntakun ti wọn ṣe lati fopin si rogbodiyan SARS.

Bakan naa ni wọn bu ẹnu ate lu ileesẹ Aarẹ ati ileegbimọ asofin pe wọn ko tete gbe igbese to yẹ lori rogbodiyan SARS to waye ọhun.

Awọn eeyan naa bu ẹnu ate lu iwọde SARS tawọn ọdọ ṣe laipe yii lati fi ẹdun ọkan wọn han lori bi awọn ọlọpaa SARS ṣe n pa awọn eeyan nipakupa, ti wọn si n hu awọn iwa aitọ gbogbo. Ohun ti wọn si sọ ni awọn ti wọn ṣe iwọde naa ṣe e lati fi doju ijọba Buhari bolẹ ni. Wọn ni gbogbo ariwo ti wọn n pa, ki wọn fi da wahaa silẹ, ti ọrọ ọhun yoo si gbe Buhari kuro nile ijọba l’Abuja ni.

Wọn ni awọn ko lodi si iṣọkan Naijiria, pe ohun to daa ju lọ ni ki Naijiria wa papọ.

Ninu ipade naa ni wọn tun ti fẹnu ko pe o ṣe pataki ki amojuto to peye bẹrẹ si i wa lori bi awọn eeyan orilẹ-ede yii ṣe n lo ẹrọ ayelujara lati maa fi pin ayederu iroyin kiri. Awọn gomina yii ni akoba nla ni eyi n ṣe fun ilẹ wa. Nidii eyi, ofin ti yoo maa de gbigbe ọrọ si ori ẹrọ ayelujara gbogbo gbọdọ wa.

Siwaju si i, awọn gomina yii ni amojuto to peye gbọdọ wa fun olu ilu wa ilẹ Abuja, ki ẹnikẹni ma ṣe iwọde tabi ifẹhonu han nibẹ debi ti wọn yoo fi ba awọn nnkan to jẹ ti ile Naijiria to wa nibẹ jẹ.

Bakan naa ni wọn tun fẹnu ko pe irufẹ ipade awọn gomina atawọn ọba ilẹ Hausa yii gbọdọ maa waye loorekoore. Bẹe gẹgẹ lawọn tun gbọdọ maa pe awọn olori ẹsin, awọn olokoowo, awọn aṣoju ọdọ, atawọn mi-in tọrọ kan paapaa sibi ipade naa.

Lọjọ naa, yatọ sawọn gomina ilẹ Hausa ti gbogbo wọn wọn wa nikalẹ, ẹni ti i ṣe ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Muhamed Adamu, naa wa nibẹ, bẹẹ ni Aarẹ ile-igbimọ aṣofin-agba, Ahmed Lawan ati olori awọn oṣiṣẹ fun ijọba Buhari, Ibrahim Gambari.

Sultan tilu Sokoto, Alhaji Saad Abubakar, lo ko awọn ọba alaye ṣodi wa sibi ipade ọhun, ninu eyi ti awọn gomina wọnyi; Inuwa Yahaya, gomina Gombe;  Abdullahi Sule, gomina, Nasarawa; Babadaru Abubakar, ti Jigawa;  Aminu Tambuwal, ti Sokoto, Nasir El-Rufai, ti Kaduna;  Bello Matawalle, ti Zamfara;  Sani Bello ti Niger ati awọn igbakeji gomina Katsina, Kogi atawọn ibomi-in loke ọya lọhun-un.

 

 

Leave a Reply