Awọn gomina ilẹ Yoruba ba Sanwo-Olu, Tinubu, Akiolu kẹdun ofo to ṣẹlẹ l’Ekoo

Aderounmu Kazeem

Awọn gomina ilẹ Yoruba ti ba Gomina Babajide Sanwo-Olu, kẹdun rogbodiyan to ṣẹlẹ l’Ekoo, bẹẹ ní wọn ke si awọn ẹṣọ agbofinro lati ṣeto aabo to peye.
Nibi ipade tawọn gomina ilẹ Yoruba ṣe nipinlẹ Ondo ní wọn tí sọrọ yii.
Ninu ọrọ alaga wọn, Amofin Rotimi Akeredolu, sọ pe ohun ibanujẹ lo jẹ bí iwọde alaafia ṣe dohun ti ẹmi rẹpẹtẹ n bọ nidii ẹ, ti ọpọ dukia tun ṣofo danu, ti awọn ọlọpaa paapaa tun ba a lọ.
O ti waa ke sí awọn ẹṣọ agbofinro lati ji giri ṣiṣẹ wọn ki eto aabo to peye le wa fawọn araalu.
Bakan naa ni wọn ba Aṣiwaju Bọla Tinubu kẹdun ofo to ṣe e nigba ti awọn ọdọ gbinaya, ti wọn sì kọlu ọpọ ileeṣẹ to jẹ ti ọkunrin oloṣelu yii.
Bẹẹ gẹgẹ lawọn gomina yii bu ẹnu atẹ lu bi awọn eeyan kan ṣe kọlu aafin Ọba Akiolu, nigboro Eko. Wọn ni ohun to buru pupọ ni.

 

One thought on “Awọn gomina ilẹ Yoruba ba Sanwo-Olu, Tinubu, Akiolu kẹdun ofo to ṣẹlẹ l’Ekoo

Leave a Reply