Awọn gomina, minisita ilẹ Yoruba ṣabẹwo ibanikẹdun si Sanwo-Olu

Faith Adebọla, Eko

Ṣe wọn ni alaṣọ lọrun paaka, o to nnkan apero fun gbogbo ọmọ eriwo, owe yii lo ṣe rẹgi pẹlu bawọn gomina ati minisita ilẹ Yoruba ṣe ko ara wọn jọ, ti wọn si lọọ ṣabẹwo ibanikẹdun si gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, latari rogbodiyan to da omi alaafia ipinlẹ naa ru logbologbo lọsẹ to kọja yii.

Nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ Aiku, Sannde yii, ni Gomina Sanwo-Olu ati Igbakeji rẹ, Ọbafẹmi Hamzat, gba wọn lalejo ni-ile ijọba, to wa ni Marina, nisalẹ Eko.

Lara awọn to ṣabẹwo naa ni Gomina ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Rotimi Akeredolu, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ati ti ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi.

Awọn minisita to wa lara ikọ naa ni gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ ri, Babatunde Faṣọla, to jẹ minisita fun eto agbara ati ile gbigbe, Ọlọrunnibe Mamora, minisita kekere fun eto ilera, Niyi Adebayọ, minisita fun okoowo ati ileeṣẹ. Awọn mi-in ti wọn tun wa nibẹ ni minisita lori ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya, Sunday Dare, minisita fun ọrọ abẹle, Rauf Arẹgbẹṣọla ati minisita fun iwakusa ati ohun alumọọni ilẹ, Ọlamilekan Adegbitẹ.

Ọkan-o-jọkan ọrọ ibanikẹdun lawọn alejo wọnyi sọ bi gomina ṣe mu wọn kiri awọn ibi ti ijamba ina ti ṣọṣẹ nipinlẹ naa. Lara awọn ibi ti Sanwo-Olu mu wọn de ni ileeṣẹ to n dari ẹru oju-omi ti wọn sun jona, ati ileeṣẹ ijọba to n ṣayẹwo ara eeyan fun ọrọ ilera, toun naa jona gburugburu.

Wọn tun fẹsẹ kan de ile-ẹjọ giga to wa ni Igboṣere tawọn janduku naa sun jona, ati awọn ile ijọba mi-in.

Awọn gomina yii koro oju si iṣẹlẹ yii, wọn si parọwa sawọn araalu pe ki wọn yẹra fun ṣiṣe idajọ buruku funra wọn nigba ti inu ba n bi wọn.

Rauf Arẹgbẹsọla lo gbadura ibẹrẹ nile ijọba, o ni ki Ọlọrun bu ororo itura sọkan awọn to padanu ẹmi ati dukia ninu ajalu to waye ọhun.

Bakan naa, Abẹnugan ile-igbimọ aṣofin apapọ, Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila ti ṣabẹwo si gomina Sanwo-Olu lori iṣẹlẹ yii, oun naa si fi ẹdun ọkan rẹ han si bawọn dukia rẹpẹtẹ ṣe ṣofo. O ni ile-igbimọ aṣofin yoo wo gbogbo ọna ti wọn le fi ṣeranwọ fun ipinlẹ Eko ti wọn ba ti wọle pada lẹnu isinmi ti wọn wa bayii.

Leave a Reply