Awọn gomina PDP mẹrin ṣepade pẹlu Mimiko l’Ondo

Jọkẹ Amọri

Ko din ni gomina ẹgbẹ oṣelu PDP mẹrin atawọn agbaagba ẹgbẹ mi-in ti wọn ṣepade pẹlu gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ, Dokita Oluṣẹgun Mimiko.

Awọn gomina naa ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde, ti ipinlẹ Rivers, Nyesome Wike, ojugba rẹ lati ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambwal, gomina ipinlẹ Abia, Okezie Ikpeazu, atawọn agbagba ẹgbẹ oṣelu PDP.

Bo tilẹ jẹ pe bonkẹle ni wọn ṣepade naa, ti wọn ko pe awọn oniroyin si i, ṣugbọn ohun tawọn to mọ bo ṣe n lọ n sọ ni pe awọn agbaagba ẹgbẹ naa waa parọwa si Mimiko lati pada sinu ẹgbẹ PDP to wa tẹlẹ ni, ni imurasilẹ fun eto idibo ọdun 2023.

Ẹgbẹ oṣelu AD ni Mimiko ti bẹrẹ gẹgẹ bii komiṣanna fun eto ilera. Lẹyin eyi lo darapọ mọ ẹgbẹ PDP, nibi to ti ṣe minisita labẹ isakoso Ọbasanjo.

Inu ẹgbẹ oṣelu Labour lo ti dupo gomina, to si wọle, ṣugbọn o pada lọ si ẹgbẹ PDP ki saa ijọba naa too tan.

Ọdun 2019 lo pada si ẹgbẹ Zenith Labour Party, nibi to ti dupo sẹnẹtọ, ti igbakeji Gomina Akeredolu, Agboọla Ajayi, naa ti dupo gomina, ṣugbọn ti awọn mejeeji ko wọle.

ALAROYE gbọ pe ipade loriṣiiriṣii ti n lọ lati ri i pe Mimiko atawọn ọmọlẹyin rẹ, to fi mọ Agbọọla Ajayi, ti i ṣe igbakeji gomina Ondo tẹlẹ naa darapọ mọ wọn.

 

Leave a Reply