Awọn gomina PDP ni ilẹ Hausa ni alaga tuntun yoo ti wa

Adefunkẹ Adebiyi

Pẹlu ibo ti awọn gomina ẹgbẹ PDP di l’Ọjọruu, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021 yii, o ti foju han gedegbe pe ilẹ Hausa ni alaga tuntun fun ẹgbẹ naa yoo ti wa bayii, nitori awọn gomina to dibo pe ilẹ Hausa lawọn nifẹẹ si pọ ju awọn ti wọn dibo fun Guusu lọ.

Ilu Abuja ni idibo naa ti waye, nile gomina ipinlẹ Akwa Ibom to wa nibẹ. Awọn gomina mẹta, iyẹn Bala Mohammed ti i ṣe Gomina Bauchi, Adamu Fintiri; Gomina Adamawa ati Darius Ishaku ti i ṣe Gomina Taraba nikan ni wọn dibo fun apa Guusu.

Awọn Gomina bii Ṣeyi Makinde(Ọyọ), Godwin Obaseki (Edo), Nyesom Wike (Rivers), Udom Emmanuel (Akwa Ibom), Ifeanyi Ugwuanyi (Enugu), Okezie Ikpeazu (Abia), Ifeanyi Okowa (Delta), Douye Diri ( Bayelsa) ati Samul Ortom ( Benue) dibo tiwọn fun Ọke-Ọya ni.

Aminu Tambuwal ti i ṣe gomina ipinlẹ Sokoto ko dibo ni tiẹ, oun lo dari eti idibo naa, oun naa si ni Alaga awọn gomina ẹgbẹ PDP.

Pẹlu ibo ti wọn di pe ki alaga tuntun ti ilẹ Hausa wa yii, ohun tawọn eeyan n sọ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ pe Guusu ni ẹgbẹ PDP yoo fi ibo aarẹ wọn fun ni 2023.

Lori eyi ti wọn ṣe yii, wọn ni wọn yoo fi abajade ẹ ranṣẹ si igbimọ to n ri si ijọba ẹlẹkun-jẹkun lẹgbẹ PDP, wọn yoo si sọrọ naa nibi ipade apapọ ẹgbẹ yii ti yoo waye ni ọgbọnjọ ati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 2021 yii.

A tun gbọ pe o ṣee ṣẹ ki wọn yẹ ọjọ ipade yii, ki wọn le raaye yanju awọn kudiẹ-kudiẹ to n lọ ninu ẹgbẹ naa, ki wọn si fẹnu ko sọna kan.

Bẹ o ba gbagbe, awọn gomina ẹkun Guusu ti pade lẹẹmeji, wọn ti ni apa ọdọ awọn lo yẹ ki aarẹ ti wa ni 2023, ṣugbọn awọn gomina ilẹ Hausa ta ko eyi, wọn ni ẹni ti ibo rẹ ba pọ ju ni yoo di aarẹ.

Leave a Reply