Awọn gomina Yoruba ni ki Naijiria pada sijọba ẹlẹkunjẹkun

Faith Adebọla, Eko

Awọn gomina ilẹ Yoruba ti dabaa pe kawọn aṣofin ṣatunṣe si ofin ilẹ wa lati faaye gba ijọba ẹlẹkunjẹkun mẹfa, eyi ti aala ilẹ ati oṣelu orileede yii pin si.

Ninu iwe kan tawọn gomina naa fi ṣọwọ sileegbimọ aṣofin apapọ lorukọ ẹgbẹ wọn (South-West Governors’ Forum) lọjọ Abamẹta, Satide, lẹyin ipade pataki kan ti wọn tilẹkun mọri ṣe pẹlu awọn aṣofin lati ẹkun Guusu/Iwọ-Oorun nileegbimọ aṣofin agba ati tawọn aṣoju-ṣofin, lopin ọsẹ ọhun.

Awọn gomina to pesẹ sipade naa ni Arakunrin Rotimi Akeredolu, to jẹ gomina ipinlẹ Ondo alaga awọn gomina iha Guusu/Iwọ-Oorun ilẹ wa, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, Gomina Ọyọ, Dokita Kayọde Fayẹmi, Gomina Ekiti, Gboyega Oyetọla, Gomina Ọṣun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, Ogun, ati Babajide Sanwo-Olu, Gomina Eko.

Lẹyin ipade naa, Akeredolu ṣalaye pe o pọn dandan lati gbe igbesẹ tawọn gbe naa tori awọn fẹẹ fi igbanu kan ṣoṣo ṣe ọja lori ibi ti ilẹ Yoruba maa duro si ninu agbeyẹwo ati atunṣe ti wọn n gbero lati ṣe siwee ofin ilẹ wa ni, o niṣe lawọn fẹẹ fi ohun kan ṣoṣo sọrọ, lai fi ti ẹgbẹ oṣelu yoowu tawọn wa ṣe.

O lawọn ti yanṣẹ fun igbimọ kan ti wọn yan nipade ọhun, lati ṣakopọ awọn erongba ati aba awọn ni ilẹ Yoruba, ki gbogbo ẹ le jẹ odidi. Ọnarebu Ọpẹyẹmi Bamidele ati Fẹmi Fakẹyẹ ni alaga igbimọ ọhun, wọn yoo si ṣiṣẹ pẹlu awọn kọmiṣanna feto idajọ lawọn ipinlẹ mẹfẹẹfa ti ilẹ Yoruba pin si.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede lẹyin ipade naa, awọn gomina naa lawọn fẹẹ ki wọn ṣatunṣe si abala kẹta, isọri ki-in-ni ati ikẹta iwe ofin Naijiria. Dipo ti isọri ki-in-ni yoo fi to awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji to para-pọ di Naijiria, wọn niṣe ni ko jẹ ẹkun mẹfa ti i ṣe Ariwa/Iwọ-Oorun, Ariwa/Ila-Oorun, Aarin-Gungbun, Guusu/Ila-Oorun, Guusu, ati Guusu/Iwọ-Oorun, ki olu-ilu si jẹ Abuja.

Bakan naa ni wọn fẹ ki isọri kẹfa fun ijọba ibilẹ lagbara lati ṣedasilẹ awọn ijọba ibilẹ ati kansu bo ba ṣe wu wọn, ki eyi si da lori iye eeyan, owo-ori ti wọn n pa wọle, ẹya ati eto isin, tabi aṣa ati orirun awọn eeyan ti wọn maa wa niru ijọba ibilẹ bẹẹ. Wọn ni ki wọn gba agbara lati ṣedasilẹ ijọba ibilẹ kuro lọwọ ijọba apapọ bo ṣe wa ni isọri karun-un ati ẹkẹfa iwe ofin ta a n lo lọwọ bayii.

Awọn gomina naa tun lawọn fẹ ki ofin wa nibaamu pẹlu awọn idajọ ile-ẹjọ giga ju lọ to waye laipẹ yii, pe gomina ko le le awọn alaga kansu danu bo ba ṣe wu u lai gba atilẹyin ileegbimọ aṣofin ipinlẹ rẹ.

Wọn tun fẹ ki wọn ṣe ayipada si isọri kọkandinlọgbọn tori o takora. Abala akọkọ nisọri yii sọ pe eeyan gbọdọ pe ọmọọdun mejidinlogun ki wọn too ka a si ẹni to le da ipinnu ṣe, ṣugbọn abala keji, ti wọn fẹẹ wọgi le e bayii, sọ pe ti obinrin kan ba ti wọle ọkọ, wọn gbọdọ ka a si ẹni to ti le da ipinnu ṣe, koda bi ko ba ti i pe ọmọ ọdun mejidinlogun.

Wọn lawọn fẹ ki apola ọrọ to maa jẹ akọmọna fun orileede wa ju “Iṣọkan ati Igbagbọ” (Unity and Faith) lọ, ṣugbọn ko yipada si “Iṣọkan ati Igbagbọ, Ọgbọọgba, Alaafia ati Itẹsiwaju” (Unity and Faith, Equality, Peace and Progress).

Leave a Reply

//intorterraon.com/4/4998019
%d bloggers like this: