Awọn Hausa ṣi n fọ ile ti wọn ko ounjẹ pamọ si kiri l’Abuja

Aderounmu Kazeem

Bo tile jẹ pe ibẹrubojo ti n mu ọpọ awọn eeyan sare da ohun ti wọn ji ko pada, ṣugbọn niṣe lawọn Hausa n fọ ibi ti ijọba ko ounjẹ pamọ si bayii, ti wọn si n ko o lọ sile wọn.

Bi a ṣe n kọ iroyin yii lọwọ, ni Gwagwalada, niluu Abuja, lawọn eeyan tun ti ri ibi ti wọn ko ọpọ ounjẹ si, ti kaluku si n di i lọ sile.

Ọkunrin Huasa kan lo mọ ọn mọ ṣe fidio kan ni tiẹ, ohun to si n sọ ni pe, “Ẹru ti emi ko ree, o si ti di temi, bii alara ṣe n ko, tawọn elomi-in naa n ko, lo jẹ ki n di i ko pọ toyii.”

Tẹ o ba gbagbe, ni kete ti Gomina Gboyega Oyetọla, ti ipinlẹ Ọṣun ti kede wi pe oun fun awọn eeyan ipinlẹ oun ni ọjọ mẹta pere ki wọn da ẹru ijọba tabi ẹru ẹlẹru ti wọn ko pada, ti wọn ko ba fẹ ri wahala ijọba lawọn eeyan ti n fi ibẹru-bojo da a pada, ṣugbọn asiko yii gan an lawọn ọmọ Hausa ṣẹṣẹ bẹrẹ si ni fọ iyara iko-ounjẹ si kiri loke ọya lọhun-un, ti wọn si n ko o lọ sile wọn.

 

Leave a Reply