Ẹni to j’ogun ko to ẹni ti ogun gbe ni Yoruba wi, beeyan ba si n fi eyi sọkan, iwọnba ni yoo du ogun ologun mọ. Ohun ti awọn ọmọ iya kan naa marun-un ko ranti ree, to fi dohun ti wọn n lu ara wọn nilukulu, ti awọn ibeji inu wọn si ṣe bẹẹ lu ẹgbọn wọn agba torukọ ẹ n jẹ Chinonso Azuatalama, pa nile wọn to wa ni Okuku, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Owerri, nipinlẹ Imo.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee to kọja yii, niṣẹlẹ naa waye. Baba kan to bimọ marun-un, to si ni iyawo kan lo ku, ni wọn ba fẹẹ pin ogun rẹ lọjọ naa. Chinonso lagba ninu awọn maraarun, ohun to si sọ ni pe ki wọn jẹ kawọn pin ogun baba awọn dọgba-dọgba, ki ẹnikan ma gba ju ẹni keji lọ.
Eyi ko tẹ awọn aburo rẹ lọrun gẹgẹ bi ẹni tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣe wi, koda, ko tẹ iya wọn paapaa lọrun, wọn si lawọn ko fẹ bẹẹ, ni wọn ba gbimọ-pọ lati pin ogun naa lai jẹ ki Chinonso ti wọn tun n pe ni Dakwada, mọ nipa ẹ rara.
Ọrọ yii lo dija lọjọ Iṣẹgun ti wọn fẹẹ pingun, lo di ohun ti aburo to tẹle Chinonso atawọn ibeji, pẹlu obinrin aarin wọn ti wọn n pe ni Chioma, fi bẹrẹ ija. A tilẹ gbọ pe iya wọn paapaa ṣegbe lẹyin awọn ọmọ rẹ mẹrin yooku, o loun ko fara mọ Chinonso rara.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Imo sọ pe Chinonso ti wọn pa yii lo kọkọ yọ ọbẹ to si n halẹ pe oun yoo gun iya oun atawọn aburo oun pa pẹlu bi wọn ṣe fẹẹ yọ oun sẹyin ninu ogun baba awọn.
Awọn aburo rẹ yooku naa bẹrẹ si i ba a ja, wọn n ja ẹṣẹ, bẹẹ ni wọn ni Chioma to jẹ obinrin inu wọn, mu iyawo Chinonso lu bii ko ku, bẹẹ, obinrin naa loyun ọmọ kẹta sinu, koda, wọn ni aboyun moṣu ko mọjọ lo wa bayii, ko ni i pẹẹ bimọ rara.
Nibi ti lilu naa ti n lọ lọwọ ni ọkan ninu awọn ibeji ti la igi nla mọ Chinonso latẹyin, n lọkurin naa ba ṣubu lulẹ, o daku lọ gbari. Wọn sare gbe e lọ sọsibitu, ṣugbọn awọn dokita sọ pe o ti ku.
Chioma to jẹ obinrin inu wọn lọwọ awọn ọlọpaa kọkọ ba, ti wọn mu un ju si gbaga. Ṣugbọn wọn ti ri ọkan mu ninu awọn ibeji to pa ẹgbọn wọn naa mu, awọn mejeeji ti dẹni ahamọ nitori Ogun.