Awọn igbesẹ to lodi sofin ti Buhari n gbe ti to idi lati yọ ọ nipo-Lamido Sanusi

Faith Adebọla

Ẹmia ilu Kano ana, Sanusi Mohammadu Sanusi keji, ti sọ pe awọn igbesẹ to lodi sofin ilẹ wa ti Aarẹ Muhammadu Buhari n gbe ti to ipilẹ fun yiyọ ọ nipo bii ẹni yọ jiga, nibaamu pẹlu ofin.

Sanusi, to ti figba kan jẹ gomina ileefowopamọ apapọ ilẹ wa (Central Bank of Nigeria) sọrọ ọhun lasiko to sọrọ bii ọkan lara awọn olubanisọrọ pataki nibi apero ọrọ-aje Naijiria (Nigeria Economic Summit) eyi to waye niluu Abuja, lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.

Sanusi ni owo banta banta ti Buhari lawọn n na lati fi di ẹdinwo ori epo rọbi lọdọọdun ti to ipilẹ fun iyọnipo Aarẹ Buhari.

“Lọdọọdun, ijọba yii n na miliọnu lori miliọnu owo dọla lori ẹdinwo owo ori epo lai gba aṣẹ ileegbimọ aṣofin lori inawo ọhun, Labẹ ofin ilẹ wa, eleyii lasan ti to ipilẹ fun yiyẹ aga mọ Aarẹ nidii, ki wọn yọ ọ danu.

Ṣugbọn ko seni to maa sọ pe lebe o pọn’mọ ire. Awọn aṣofin ki i bi wọn leere ọrọ ohun ti wọn ba ṣe.”

Sanusi tun sọ pe awọn ipinnu tijọba n ṣe n ṣe ipalara fun orileede yii, o si n ko ba ọrọ-aje rẹ.

“Ohun tawọn to n ṣejọba yii o mọ ni pe o san lati ṣepinnu to maa mu idagbasoke ba ilu ju ki wọn ṣepinnu to maa ṣe awọn ọtọọkulu nikan lanfaani lọ.

A n ṣepinnu to daa loootọ, bii ki owo epo rọju, ki owo naa rọju, ki owo Naira lagbara si i, ṣugbọn nigbẹyin, ki lawọn ipinnu wọnyi n na wa, ere ki lo wa nibẹ ti a ba ko owo to yẹ ki wọn na sori eto ẹkọ, ta a lọọ da a sori sisan adinku ori epo rọbi.”

Leave a Reply