Awọn ileeṣẹ ibanisọrọ ti laṣẹ lati fun awọn eeyan ni nọmba idanimọ orileede (NIN) bayii

 Faith Adebọla

 Ijọba apapọ ti fọwọ si i, wọn si ti fawọn ileeṣẹ ibanisọrọ laṣẹ lati ṣoju fun ajọ to n pese kaadi ati nọmba idanimọ (NIN) fawọn araalu, kawọn naa le bẹrẹ si i pese awọn nọmba idanimọ naa.

Ọga agba ajọ to n mojuto ọrọ idanimọ ọmọ orileeede (National Identity Management Commission, NIMC), Ọgbẹni Aliyu Aziz, lo sọ eyi di mimọ l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, niluu Abuja.

O nijọba gbe igbesẹ yii lati mu ki nnkan tubọ rọrun fawọn araalu ti ko ti i ri nọmba idanimọ gba, ati lati mu adinku ba ero witiwiti to n ya bo awọn ọfiisi ileeṣẹ NIMC, ti wọn n fẹ lati forukọ silẹ fun nọmba ati kaadi idanimọ ọhun.

O ni igbesẹ yii tun pọn dandan lati dena akoran arun Koronafairọọsi to n ran bii ina ọyẹ lasiko yii, tori ijọba ko fẹẹ fi ẹmi awọn eeyan sinu ewu.

Ohun ti igbesẹ yii tumọ si ni pe awọn ileeṣẹ ibanisọrọ nilẹ wa, bii MTN, Globacom, Airtel, 9mobile atawọn mi-in yoo le forukọ awọn eeyan silẹ, ki wọn si pese nọmba idanimọ (National Identity Number, NIN) fun wọn.

O waa rọ awọn eeyan lati fọwọ sowọ po pelu ijọba, ki wọn si tẹle awọn aṣẹ ati ilana to rọ mọ eto gbigba nọmba ati fifi nọmba naa sori akọsilẹ nọmba tẹlifoonu ẹni kọọkan, ṣaaju ọjọ ti gbedeke tijọba fun awọn ileeṣẹ ibanisọrọ yoo fi pe, ti wọn yoo si pa nọmba SIM ẹni ti ko ba forukọ silẹ rẹ.

Leave a Reply