Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe awọn ileewe ipinlẹ naa yoo ṣi lọjọ kẹta, oṣu to n bọ, fawọn to wa ni kilaasi aṣekagba.
Gomina Babatunde Sanwo-Olu lo kede ọrọ naa lonii, ọjọ Ẹti, Furaidee, o si ni awọn ileewe to jẹ tojoojumọ ni eyi wa fun, ki i ṣe eyi tawọn akẹkọọ n gbe ninu ọgba.
Awọn to lanfaani lati wọle ni awọn to wa ni kilaasi aṣekagba nileewe alakọọbẹrẹ, ipele kẹta ileewe girama ati ipele kẹfa ileewe girama.
Ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹta, ọdun yii, nijọba Eko kede pe awọn ileewe ti di titi pa latari arun koronafairọọsi to gba ilu kan.
Lọwọlọwọ, awọn to le lẹgbẹrun mẹwaa (10, 823) lo ti lugbadi arun naa nipinlẹ ọhun.