Awọn ileewe ilẹ Yoruba yoo ṣi loṣu to n bọ

Oluyinka Soyemi

Awọn ileewe to wa lawọn ipinlẹ mẹfẹẹfa nilẹ Yoruba yoo ṣi lọjọ kẹta, oṣu to n bọ.

Iwọle naa ni wọn fọwọ si lati jẹ kawọn ọmọ ileewe girama ṣe idanwo aṣekagba WAEC.

Eyi waye lẹyin ipade ẹgbẹ itẹsiwaju ilẹ Yoruba ti wọn n pe ni DAWN waye.

Wọn pinnu lati ba ajọ to n ṣegbatẹru idanwo naa sọrọ ki wọn le sun ọjọ idanwo siwaju diẹ sipari oṣu to n bọ, bẹẹ ni apero yoo waye pẹlu ijọba apapọ.

Bakan naa ni DAWN ṣetan lati ri i daju pe gbogbo eto imọtoto lawọn ipinlẹ tẹle lasiko idanwo naa.

 

Leave a Reply