Awọn ileewe to n fa wahala lori Hijaabu di abawọle ileewe wọn pa n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Latari aṣẹ tijọba Kwara pa fun gbogbo awọn ọga ati olukọ ileewe ti wahala ti n ṣẹlẹ lori ọrọ lilo hijaabu lati pada sẹnu iṣẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, wamuwamu lawọn ọmọ ijọ Kerubu ati Serafu duro si abawọle ileewe C & S to wa niluu Ilọrin lati ma gba ẹnikẹni laaye lati wọle.

Awọn ileewe mẹwẹẹwa ti wahala ti n ṣẹlẹ lori hijaabu ni; C&S College, Sabo-Oke; St. Anthony’s Secondary School, Offa Road; ECWA School, Ọja Iya; Surulere Baptist Secondary School, Bishop Smith Secondary School, Agba Dam, CAC Secondary School, Asa Dam; St. Barnabas Secondary School, Sabo-Oke; St. John School Maraba; St. Williams Secondary School, Taiwo Isale, ati St. James Secondary School, Maraba.

ALAROYE ṣakiyesi pe awọn ọmọ ijọ naa ninu aṣọ funfun pẹlu amure ti wọn san mọdii n kọrin ti wọn si n gbadura kikankikan bii awọn afadura-jagun, lati ta ko bi wọn ṣe ni ijọba fẹẹ kan Hijaabu le awọn ọmọ wọn lori.

Yatọ si awọn ọmọ ijọ to di gbogbo iwaju geeti to wọnu ọgba ileewe naa, wọn tun ja loodu yẹẹpẹ siwaju ibẹ lati dina awọn olukọ atawọn akẹkọọ.

Bakan naa lọrọ ri ni ileewe Saint Anthony atawọn mi-in. Awọn olukọ ati ọga ileewe wa gẹgẹ bii aṣẹ tijọba pa, ṣugbọn nigba ti wọn ko raaye wọle wọn duro kaakiri, ti wọn si n jiroro.

Nibi ti awọn ọmọ ijọ duro si lawọn agbofinro ti ya bo wọn ti wọn si fi tipa ṣi abawọle awọn ileewe naa.

Ni ileewe Baptist, nibi ti rogbodiyan ti ṣẹlẹ laipẹ, alaafia ti pada sibẹ bayii pẹlu bawọn olukọ ṣe wa nikalẹ.

Leave a Reply