Awọn iwa Buhari lẹgbẹ Afẹnifẹre fi kọ lati ṣatilẹyin fun un lasiko idibo to kọja -Faṣọranti

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Reuben Faṣọranti, ti ni ọkan-o-jọkan iwa ibajẹ pẹlu eto aabo to mẹhẹ to n sẹlẹ lọwọ labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari ti fidi ohun ti ẹgbẹ naa fi kọ lati ṣatilẹyin fun un ninu eto idibo gbogbogboo to waye lọdun 2015 ati 2019 mulẹ.

Baba ẹni ọdun marundinlaaadọrun-un yii lo sọrọ naa ninu ọrọ to bawọn oniroyin sọ lasiko ti wọn n ṣayẹyẹ aadọrin ọdun ti wọn ṣe ifilọlẹ ẹgbẹ Afẹnifẹre lorilẹ-ede Naijiria.

O ni lati bii ọdun mẹfa sẹyin ti iṣakoso Aarẹ Buhari ti bẹrẹ ni ko ti fi bo rara pe ijọba to kun fun iwa ibajẹ ati ẹlẹyamẹya loun n ṣe.

Yatọ si ipenija eto aabo to n bawọn eeyan finra eyi ti apa Aarẹ ko ka mọ, awọn arufin to yẹ kijọba ti yọ nipo latari iwa ibajẹ kan tabi omiran ti wọn hu lo ni wọn ṣi wa ninu iṣakoso rẹ ti wọn jọ n ṣejọba.

O ni ọdun keji ree tawọn ọlọpaa ti n ṣewadii lori awọn to yinbọn pa ọmọ oun loju ọna marosẹ Ọrẹ lasiko to n lọ si ibugbe rẹ niluu Eko, ṣugbọn ti wọn ko ti i rojutuu iwadii ọhun titi di asiko yii.

Oloye Faṣọranti ni bi awọn ko tilẹ sọrọ jade, o yẹ kawọn eeyan orilẹ-ede yii ti ri aridaju idi ti ẹgbẹ Afẹnifẹre ṣe kọ lati ṣatilẹyin fun Buhari lasiko to fi n dupo aarẹ.

Lẹyin eyi lo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun mimu ẹgbẹ naa duro lati bii aadọrin ọdun sẹyin pẹlu gbogbo ipenija tí wọn ti la kọja lati aye NADECO.

Leave a Reply