Awọn ‘Iya ooṣa’ naa jade fun iwọde ‘Yoruba Nation’

Faith Adebọla

O da bii pe ki i ṣe awọn ọdọ nikan ni ọrọ orileede Yoruba yii ka lara bayii o. Awọn ọmọde, agbalagba, to fi mọ awọn iya olooṣa ni wọn wọ aṣọ funfun, ti wọn so ilẹkẹ m’ọrun, ti wọn mu aja wọn lọwọ ti wọn n mi in kolokolo, tawọn naa si dara pọ mọ awọn to n ṣe iwọde ‘Oodua Nation’.

Ariwo ti awọn iya to to lọwọọwọ ni abẹ biriiji Ọjọta yii n pa ni pe ‘Oodua Nation la fẹ,’ ‘Ẹ fun wa ni Orileede Oodua.’ ‘Iya to n jẹ wa yii ti to gẹ’, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Koda, nibi tọrọ yii le de, awọn ọmọ keekeeke ti ko ju ọmọ ọdun mẹfa si meje lọ naa ba ALAROYE sọrọ nibi iwọde yii, awọn ọmọ naa ni awọn ko ri ounjẹ jẹ, nnkan ti wọn, omi inu ọra tawọn n ra ni naira mẹwaa ti di ogun naira, miniraasi naa ti gbowo lori. Lawọn ọmọ yii naa ba n sọ pe Yoruba Nation lawọn fẹ.

Leave a Reply