Awọn janduku agbebọn yinbọn pa ọga ṣọja l’Abuja, wọn tun ji aburo ẹ gbe

Faith Adebọla

Ko jọ pe awọn janduku agbebọn to n fojoojumọ ṣoro bii agbọn nilẹ wa lasiko yii bẹru ẹnikẹni mọ bayii pẹlu bi wọn ṣe ṣakọlu si ọga ṣọja ilẹ wa kan, Mejọ Jẹnẹra Hassan Ahmed, ti wọn si fibọn gbẹmi ẹ loju-ẹsẹ.

Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o waye nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee yii, lagbegbe Abaji, niluu Abuja, olu ilu ilẹ wa.

ALAROYE gbọ pe oloogbe naa ati aburo ẹ tawọn eeyan kọkọ ro pe iyawo ẹ ni, ni wọn jọ n dari re’le ninu ọkọ ayọkẹlẹ wọn lati ilu Okene ti wọn rinrin-ajo lọ, lọna marosẹ Lọkọja si Abuja. Dẹrẹba to n wa ọkọ naa, Sajẹnti Bukar, lo ṣikẹta wọn ninu ọkọ ọhun.

Wọn ni bi wọn ṣe de agbegbe Abaji yii, lawọn agbebọn naa yọ si wọn lojiji, wọn si gbiyanju lati da ọkọ ayọkẹlẹ naa duro, ṣugbọn dẹrẹba naa ṣapa lati sa mọ wọn lọwọ, ni wọn ba ṣina ibọn fun wọn.

Ibọn ti wọn yin leralera ọhun lo ba Ọgagun Hassan, wọn ni ori nibọn naa ti ba a, ẹsẹkẹsẹ lo si ti ku.

Wọn tun yinbọn fun dẹrẹba ọkọ naa, ibọn ọhun si mu-un, ṣugbọn ko ku, niṣe ni wọn lo dọgbọn ṣe bii ẹni ti ku bo ṣe diju mọri nidii siarin (steering) ọkọ ọhun, boya eyi lo mu kawọn agbebọn naa ro pe oun naa ti ku, ni wọn ba paṣẹ fun aburo rẹ, Safina Ahmed, nibi to doju bolẹ si lẹyin ọkọ ọhun, wọn si wọ ọ wọgbo lọ.

Ileeṣẹ ologun ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. Ninu atẹjade kan ti Alukoro wọn, Ọgagun Onyema Nwachukwu, fi lede laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, o ni ikọ awọn ọmoogun ti tẹle Ọgagun Anthony Omozoje lọọ ṣabẹwo ibanikẹdun siyawo oloogbe naa ti wọn sọ di opo lojiji.

Bakan naa ni igbakeji Aarẹ ẹgbẹ awọn iyawo ṣọja ilẹ wa, Abilekọ Stella Omozoje naa ti ṣabẹwo siyawo Ahmed, wọn si ti duro lati tu u ninu.

Onyema lawọn maa ṣẹyẹ ikẹyin fun oloogbe yii laago mẹwaa owurọ ọjọ Ẹti, nilana awọn ologun ki wọn too sinku rẹ si itẹkuu ologun to wa ni Bareke Lungi, niluu Abuja, lawọn maa ṣeto naa.

A gbọ pe nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin ni ọga ṣọja to ṣẹṣẹ gbapo, Ọgagun Farouk Yahaya, yan oloogbe naa sipo Provost Mashal awọn ọmoogun ilẹ wa, wọn si tun fun un ni igbega sipo darẹkitọ nileeṣẹ ologun.

Leave a Reply